Rochas Okorocha in court: Kí ló gbé Rochas Okorocha dé ilé ẹjọ́?

Owele Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, BBC Igbo

Iroyin ti jade pe o ṣeeṣe ki gomina ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha tẹlẹ foju ba ile ẹjọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Imo, Ikeowo Orlando sọ fun BBC pe lootọ ni awọn fi panpẹ ofin Sẹnetọ Rochas ni ọjọ kọkanlelogun oṣu keji lẹyin to fi tipatipa lọ ibi dukia kan.

Okorocha to n ṣoju ẹkun Imo West nile igbimọ aṣofin agba naa ni gomina ipinlẹ ọhun laarin ọdun 2011 si 2019.

Gẹ́gẹ́ bi Orlando ṣe sọ ọ, ijọba to wa lori alefa lọwọlọwọ gbe agbegbe kan Royal Spring Palms apartment ti pa ṣugbọn wọn ni Rochas ja wọ ibẹ.

Àkọlé fídíò, Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede

Eleyi mu ki ọpọlọpọ aṣoju ijọba atawọn ọdọ ilu Owerri korajọ ti wahala si bẹ silẹ laarin igun mejeji ti ọrọ ti ṣẹlẹ.

"A pe Sẹnetọ Rochas Okorocha si ileeṣẹ wa lati wa sọrọ ohun to m nipa fifi ipa ja wọ inu ọgba naa".

Ṣaaju, ijọba ipinl Imo gbe Royal Palm Estate ti pa eyi to jẹ ohun ini kan ti wọn lọ mọ Nkechi Okorocha to jẹ iyawo Sẹnetọ Rochas lẹsẹ eyi to wa ni agbegbe Akachi ni olu ilu Owerri.

Ki lo ṣẹlẹ gangan?

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Sẹnet Rochas fi sita, Sam Onwuemeodo sọ pe ijọba ipinlẹ Imo dari awọn janduku ati ọlọpaa lati ile ijọba lati lọ kọlu gomina tẹlẹ.

O ni wọn ba gbogbo ọkọ to n tẹle e jẹ. O tun fi kun un pe wọn kọlu awọn oluranlọwọ rẹ amọ Rochas ko awọn eeyan tirẹ lọ ja ilẹkun ti wọn si wọ ile naa.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Imo ti ni awọn ko lọwọ si iṣẹlẹ yii.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Oluranlọwọ ti gomina Uzodinma, Oguike Nwachukwu sọ pe ijọba gbe ile naa ti torii pe ẹru ole ni.

O ni nigba ti Rochas si ko awọn janduku lọ ja ilẹkun, ojuṣe ọlọpaa ni lati rii daju pe awọn eeyan tẹle ofin ilu.