Arsenal vs Manchester United: Arsenal borí i Manchester United ní Premier league

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbo ewuro si oju Manchester United lọjọ aiku ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier league ilẹ Gẹẹsi to waye ni papa iṣire Emirate.
Ami ayo meji si odo ni Arsenal fi gbẹyẹ mọ Manchester United lọwọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Xhaka lo gba goolu akọkọ wọle ni iṣẹju kejila ifẹsẹwọnsẹ naa, nigba ti Aubameyang gba gbeelẹ ko gba si goli, (Penalty) wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mọkandinlaadọrin.
Pẹlu esi yii Arsenal yoo maa fi ami meji la Manchester United lori atẹ liigi ilẹ Gẹẹsi pẹlu bi ere ije tani yoo wa laaarin ipo mẹrin akọkọ ninu liigi naa ṣe n gbona sii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii ọpọ itakurọsọ lo ti n waye laarin awọn onwoye, onimọ ere bọọlu atawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji lori pataki ifẹsẹwọnsẹ ọhun fun ati kopa awọn mejeeji ninu idije Champions league ni saa bọọlu to n bọ.
Arsenal lo fi o to gẹẹ si irinajo olubori ti Manchester United ti bẹrẹ si nii rin lati igba ti olukọni wọn, Ole Gun Solkjaer ti gba iṣẹ ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kejila ọdun to 2018.
Igba akọkọ ni yii ti Manchester United yoo maa fidirẹmi ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi lati oṣu kejila ọdun 2018. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn ti gba lati igba naa, wọn bori mẹwaa wọn si ta ọmi meji.











