Americans in Africa: Wo ìdí tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan ṣe ń kó bọ̀ wá fi ilẹ̀ Áfríkà sebùgbé

Ọpọ awọn eeyan nilẹ Afirika lo n gbiyanju lati tẹkọ leti lọ si Amẹrika lati fi ibẹ ṣebugbe, ṣugbọn awọn adulawọ kan to jẹ ọmọ Amẹrika ti bẹrẹ si nii sa kuro lọhun lati maa wa gbe nilẹ Afrika.
Lara irufẹ awọn bẹẹ ni Brian, Rukiya ati Marcus ti wọn fi Amẹrika silẹ lọ si Namibia, Tanzania ati Uganda lati maa gbe.
Awọn eeyan naa sọ fun BBC pe eredi ti wọn ṣe fi Amẹrika silẹ ko ṣẹyin bi iwa ẹlẹyamẹya ṣe di tọrọfọnkale nibẹ.
- A ṣe sùúrù tó, ọmọ wa ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀gá fásitì UI lọ́tẹ̀ yìí - àkóríjọ́ ẹgbẹ́ ọmọ Ibadan
- Kí ni ìjọba Ogun sọ nípa N25, 000 owó àyẹ̀wò COVID-19 fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò wọlé padà?
- A ṣì ń ṣèwádìí lọ́wọ́ lórí àwọn t'ọ́ta ìbọn pa lọ́jọ́ ọdún Eid n'Ibadan - Ọlọ́pàá
- Kí ló dé tí Shoprite fẹ́ kógbá kúrò ní Nàìjíríà?
Marcus Pace sọ pe oun ti maa n ṣabẹwo si Ugandan loorekoore lati ọjọ to ti pẹ, ṣugbọn oun ti wa pinnu lati fidi mọlẹ si Afrika bayii.
O ni o rọrun lati gbe nilẹ adulawọ ju ati gbe ni Amẹrika lọ nitori iṣe ni oun maa n ṣe ni gbogbo igba latari awọn owo ori gọbọi atawọn nnkan miran.
Marcus ṣalaye pe ọkan oun balẹ nitori ko si ẹni to n gbiyan lati yin oun nibọn nitori pe oun jẹ alawọ dudu.
Bakan naa ni arabinrin Rukiya McNair ni inu awọn ọmọ oun dun pupọ lati gbe nilẹ adulawọ.
O ṣalaye awọn oun ti oju rẹ ri nigba to n dagba nilẹ Amẹrika, paapaa julọ lori iwa idẹyẹsi ati ẹlẹmẹyamẹya to n waye lagbegbe ti oun dagba si, eyii to jẹ pe awọn alawọ funfun lo pọju nibẹ.
Rukiya ni afojusun oun ni lati gbe nibi ti yoo fi oun lọkan balẹ ti yoo si dabi ile fun oun.
O ni orile-ede Tanzani, nilẹ Afrika ni oun ti ni ifọkanbalẹ ti oun n fẹ tọmọ-tọmọ.
Ọgbẹni Brian Wheeler ti lo ọdun mọkanla nilẹ Afrika, botilẹ jẹ pe ọmọ bibi Amẹrika ni, o ni ilẹ Afrika ni oun ri gẹgẹ bi ile.
Awọn eeyan naa ṣalaye fun BBC pe ọpọ igba ni awọn eeyan l'Amẹrika ma na sọrọ abuku si wọn nitori awọ ara wọn.
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ọhun ko mọ ara wọn ri, ṣugbọn ero wọn ṣọkan pe, ko si ibi to dabi ile, ilẹ Afrika si ni ile fun wọn.
Lori boya wọn ṣi lee pada silẹ Amẹrika, awọn eeyan ọhun fohun ṣọkan pe ohun kan ṣoṣo to lee gbe wọn pada lọ Amẹrika ni ki wọn lọ ṣe abẹwo si awọn ẹbi to wa lọhun, bi bẹẹ kọ, Afrika ni ile ti wọn yan laayo.














