Novak Djokovic: Ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù tẹníísìì Novak Djokovic ti lùgbàdì coronavirus

Novak Djokovic

Oríṣun àwòrán, Instagram/djokernole

Gbajugbaja agbabọọlu tẹnisii, Novak Djokovic ti lugbadi aarun coronavirus.

Oun ni agbabọọlu tẹnisii to ṣẹṣẹ ko aarun covid-19 lẹyin ti Grigor Dimitrov, Borna Coric ati Viktor Troicki sọ pe awọn ni coronavirus lẹyin ti wọn koju Djokovic ninu idije Adria Tour.

Troicki ti oun naa jẹ ọmọ orilẹede Serbia ni Djokovic kọkọ koju ki o to koju Dimitrov ati Borna Coric.

Ẹwẹ, gbajugbaja agbabọọlu tẹniisi ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Andy Murray ni ẹkọ nla ni awọn agbabọọlu tẹniisi to lugbadi coronavirus jẹ fawọn yoku.

Ọmọ ilẹ Australia, Nick Kyrgios ni tiẹ sọ pe igbesẹ lati maa kopa ninu idije tẹniisii lasiko ajakalẹ aarun covid-19 yii.

Borna Coric, Grigor Dimitrov ati Novak Djokovic

Oríṣun àwòrán, Instagram/djokernole

Lati oṣu keji ọdun 2020 ni ajọ to n ri si ere idaraya tẹniisii, ATP ti fote le tẹniisii gbigba nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Idije Adria Tour wa lara awọn idije tẹniisii to ṣẹṣẹ bẹrẹ laipẹ yii.