Chelsea: Chelsea dun DJ Cuppy nínú lẹ̀yìn tí Arsenal gba omijé lójú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọda oro koda bi bi ada gbẹyin ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gan an lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa to kọ lẹta si iya lọwọ Chelsea.
Aston Villa lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Ṣugbọn Chelsea fi ye wọn pe agbo to tadi mẹyin, agbara lo lọ mu wa ni abala keji ere bọọlu naa.
- Cuppy kọ Arsenal sílẹ̀! Ọmọ Otedola bú sẹ́kún lẹ́yìn tí Brighton tún d'ẹrù ìyà lé Arsenal lórí
- Wo àwọn oníròyìn méje tó kú láàrin ọjọ́ méje ní Nàìjíríà
- Wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà tó yẹ kí ayé parẹ́ àtàwọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà
- Báwó ni òògùn dexamethasone ṣe ń ṣiṣẹ́ lára
- Ó di gbéré! Arẹwà Ibidunni Ighodalo wọ káà ilẹ̀ lọ nílùú Eko
- Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo Agboola Ajayi ti fẹgbẹ́ APC sílẹ̀ lọ PDP
Christian Pulisic lo kọkọ dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di wakati kan.
Lẹyin iṣẹju meji pere si igba naa ni ẹlẹsẹ ayo Olivier Giroud fi ọba le fun Chelsea eyi ti o mu Chelsea siwaju pẹlu ayo meji sodo.
Awọn kan tiẹ sọ pe ẹbun ayẹyẹ ọjọ ibi ni awọn agbabọọlu Chelsea fi ijaweolubori ninu ere bọọlu naa ṣe fun akọnimọọgba wọn Frank lampard to pe ọdun mejilelogoji lọjọ Abaméta.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹwẹ, lẹyin ti Florence Otedola ti ọpọ mọ si Chelsea DJ kọ Arsenal silẹ pẹlu omije loju, o ti kede loju opo Twitter rẹ pe oun fẹran ohun ti oun ri lara ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.
Amọ o ṣalaye pe oun si ni lati wo awọn ẹgbẹ agbabọọlu mi ki oun to pinu eyi ti oun maa darapọ mọ.












