Wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín owó oṣù òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀èdè Áfríkà yòókù

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn ọmọ orilẹedeNaijria lo n reti lati mọ iye owo ti ijọba yoo kede gẹgẹ bii owo oṣu tuntun fun awọn osisẹ sugbọn ti a ba ni ki a wo itan, eyi ki ṣe tuntun rara.

Awọn oṣiṣẹ koroju si ikede ijọba apapọ to kede pe oun ti fi ida marundinlogo kun owo oṣu awọn osisẹ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ni ikede yii ko si lara adehun ti awọn ni pẹlu ijọba apapọ.

Labour n bere lọwọ ijọba apapọ pe ki wọn fi owo kun owo oṣu lati N30,000 si N615,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere ju fun awọn oṣisẹ.

Lọdun 2019, iṣejọba Aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari gba lati ma san ọgbọn ẹgbẹrun naira gẹgẹ bii owo oṣu to kere fun awọn osisẹ - eyi to kere si US $21.50 to jẹ owo okere.

Ninu alaye yii, a yoo wo iyatọ to wa ninu owo oṣu awọn osisẹ Naijiria ati awọn orilẹede Afrika yooku.

Owo oṣu ti ijọba South Africa ati Gabon n san jẹ ilọpo mọkanla owo osisẹ Naijiria.

Bo ti jẹ pe Orilẹede South Africa ati Naijiria maa n figagbada ti a ba n sọrọ nipa idagbasoke eto aje ni ilẹ Afrika.

Gẹgẹ bii ofin ṣe gbe kalẹ, owo oṣu to kere ju ni South Africani R4,405.60 ti iye rẹ ni Naira jẹ N325,365.93 tabi $235.98

Eyi tumọ si pe owo oṣu to kere ju ni Gabon jẹ ilọpo mọkanla si eyi ti Naijiria n san.

Gabon, jẹ orilẹede to wa ni aarin gbogbo Afrika ti awọn osiṣẹ rẹ n gba owo to kere ju laarin awọn orilẹede yooku ni agbegbe naa.

Ijọba rẹ n san owo oṣu to kere ju ni 150,00 CFA ti iye rẹ ni Naira jẹ 335,960(US$244.70)

Eyi jẹ ilọpa mejila ohun ti Naijiria n san fun awọn osisẹ

Ti a ba tun wo Ivory Coast, ofin ni owo to kere ju ni CFA7500- ti iye ni naira jẹ 167,9789(US122.35)

Iye yii ilọpo mẹfa owo oṣu ti Naijiria n san.

Bakan naa ni Senegal, ọmọ ẹgbẹ ECOWAS pẹlu Naijiria n san owo oṣu to kere ju ni CFA70,000 , ti iye ni naira jẹ 156,780(US$144.19)

Ki lo n ṣẹlẹ ni Niger ati Cameroon?

Ni awọn orilẹede to sumọ orilẹede Naijiria, bi Niger ati Cameroon, owo oṣu ti wọn san fi diẹ pọ ju ohun ti Naijiria n san.

Owo oṣu to kere ju ni Niger bi CFA 30,000 ti iye rẹ jẹ ni naira 67,191 (48.94US)

Ni Cameroon owo oṣu to kere ju ni CFA 43,969, ti iye rẹ ni naira jẹ N98,478($71.73)

Wo iye owo oṣu to kere ju ti orilẹede mọkanla ni Afrika n san

  • Niger cfa30000 = $48.94
  • Senegal cfa70,000 = $114.19
  • Ivory Coast cfa75,000 = $122.35
  • Gabon cfa150,000 = $244.70
  • Cameroon cfa43,969 = $71.73
  • Kenya Sh15,202.00 = $114.69
  • Uganda USh130,000 = $34.21
  • Tanzania TZS150,000 = $57.89
  • Rwanda RF29,000 = $22.46
  • Somali SOS39,600 = $28.92
  • Ethiopia ETB1,150 = $19.86
  • South Africa 4,405.80 = $235.98

Fifi owo kun owo oṣu tabi ki koju eto aje to mẹyẹ?

Dokita Bashir Muhammed Achida jẹ olukọ ni ẹka isiro ni fasiti Usmanu D’anfodio niluu Sokoto ni oun gbagbọ pe fifi owo kun oṣu ko ki n ṣe ọna abayọ si isoro ọwọn gogo to gba o de lorilẹede Naijiria.

“A le tẹ owo sugbọn ko ni iyi. Ni ilu ti a ti n fi owo nla ran nnkan kekere,” O sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC.

O ni ijọba lati iṣejọba Obasanjo si Jonathan ati Buhari lo fowo kun owo oṣu awọn osisẹ sugbọn sibẹsibẹ ilu o fararọ.

O tẹsiwaju pe o ṣe koko ki ẹgbẹ osisẹ pe ijọba joko pe ki wọn wa ojutu si iṣoro ọrọ aje dipo fifi owo kun owo oṣu.

“Nnkan mẹta ni ijọba ni lati moju to, ki wọn fowo kun owo oṣu wọn, eto ẹkọ, eto ilera ati ipese ounjẹ”