Kí ló fa aáwọ̀ tó jẹ́ káwọn afurasí jàndùkú dáná sun ọjà Ile-Epo l'Eko?

Oríṣun àwòrán, @AceDKid169306/X
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti fọwọ ṣinkun ofin mu aadọta afurasi janduku ti wọn dana sun ọja Ile-Epo lagbegbe Abule Egba nipinlẹ Eko ni Ọjọbọ ọjọ keji oṣu Karun ọdun 2024 yii.
Rogbodiyan to bẹ silẹ l'ọja naa lo ṣokunfa bi ọpọ dukia ati ọja to to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ti ṣofo.
Ọpọ k'ẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti ọpọ mọ si kẹkẹ Marwa ati ọkọ ni wọn danu sun nibi rogbodiyan ọhun.
Ninu ọrọ rẹ nipa iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Bẹnjamin Hundeyin ṣalaye pe DPO ọlọpaa agbegbe Oke-Odo lo ko awọn ọlọpaa lọ si ọja naa lati dawọ rogbodiyan naa duro.
Hundeyin sọ pe "lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi ọwọ ofin mu aadọta janduku tan, wọn to wo ibi ti wọn fi ṣe ibugbe lẹgbẹ ọja Ile-Epo.
Koda, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Adegoke Fayoade, ti paṣẹ pe ki awọn afurasi janduku ti ọwọ tẹ lori ìṣẹlẹ naa foju ba ile ẹjọ ni kiakia.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni beṣu bẹgba lati fiya jẹ ẹnikẹni to ba tapa sofin tabi to ba n da omi alaafia ilu ru."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki lo fa rogbodiyan to bẹ silẹ l'ọja Ile-Epo nítosí Abule Ẹ̀gba?
Gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe sọ, alẹ Ọjọru ni aawọ naa ti bẹrẹ nigba ti ẹni to ni ṣọọbu ti wọn ti ta tẹtẹ kan kọ lati fun ọkan lara awọn tọọgi to jẹ N14,000 ni owo to jẹ.
Ọrọ yii gan an ni wọn sọ pe o fa aawọ ti o ṣi pada di nnkan nla.
Ọkan lara awọn ontaja ninu ọja Ile-Epo, Aminu Muhammad Sai'd naa salaye pe tẹtẹ lo fa rogbodiyan to ṣẹlẹ l'ọja ọhun.
Sai'd ni ija bẹ silẹ lẹyin ti ẹni to ni ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹtẹ kọ lati fun ẹni to jẹ owo ni gbogbo owo to jẹ.
"Lẹyin naa l'awọn janduku ya wọ ọja Ile-Epo ti wọn si lo anfaani ija to bẹ silẹ lati ṣiṣẹ ibi wọn.
Ni ṣe ni wọn bẹrẹ si ni jale ti wọn si tun fi ina si ọja.
Oriṣiiriṣii ọja olowo iyebiye ni wọn ji ko lọ ninu awọn ṣọọbu ninu ọja Ile-Epo," Sai'd lo sọ bẹẹ.















