Wo bí òfìò, ohun jíjẹ tó kéré yìí ṣe wúlò fún ìlera rẹ tó

Aworan ofio ninu abọ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ofio gbajumọ ni nnkan jijẹ kaakiri orilẹ-ede yii. Yatọ si pe o dun lẹnu, anfaani ara rẹ fun takọ-tabo tun kọja a n dakẹ si.

Oloyinbo n pe e ni Tiger nut, ofio ni Yoruba mọ ọn si, Hausa n pe e ni Aya, nigba ti awọn Igbo n pe e ni Aki Hausa. Awọn ẹlomi-in si maa n pe e ni ẹpa Hausa.

Loootọ ni ofio kere loju, ṣugbọn atare kere ni, eeyan ko ni i jẹ koro kan rẹ ko ma ta lẹnu. Bẹẹ ni ofio naa ri nipa iṣẹ rere to n ṣe fun ara eniyan.

Koda, ohun mimu ti wọn fi ofio ṣe ni awọn kan gbagbọ pe, o maa ran ibalopọ lọwọ laaarin takọ-tabo, eyi si jẹ ko di aayo fun awọn to mọ ọn.

Ṣugbọn laipẹ yii ni ijọba Eko kede pe Kọlẹra to bẹ silẹ lẹnu ọjọ mẹta yii ko ṣẹyin nnkan mimu ti wọn fi ofio ṣe yii, eyi ti a mọ si ‘Tiger nut drink.’

Wọn ni awọn kan ti imọtoto wọn ko ṣee fẹsẹ ẹ mulẹ ninu awọn to n ṣe e lo fa Kọlẹra to gbode.

Ikede yii ti mu ọpọ eeyan ṣọra fun nnkan mimu olofio, ṣugbọn bi ko ba si eyi, ofio gbayi l’Afrika, apa kan Asia ati orilẹede Spain.

Latilẹ, ofio ki i ṣe eso onikoro, ẹya ounjẹ ti wọn maa n wà bii iṣu ni, bo tilẹ jẹ pe wọn ki i tobi bii iṣu. Awọ iyẹpẹ ilẹ (brown) ni wọn si maa n ni.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi o ba jẹ ofio, yoo maa da bi agbọn lẹnu. Awọn eeyan yoo maa tu fulufulu to ba jade nigba ti wọn ba n jẹ ẹ nu, wọn ki i gbe e mi.

Ọmọwe Abosede Olowofoyeku, ẹni to gboye nipa iwadii oogun ati awọn nnkan ti Oluwa da, ṣalaye fun BBC pe "Irugbin ti a maa n wa nilẹ bii iṣu ati ẹpa ni ofio."

Ọmọwe Olowofoyeku ṣalaye pe anfaani ilera to wa ninu nnkan mimu ti wọn fi ofio ṣe ju ti Kunu lọ.

O ni iyẹn lo ṣe jẹ pe ohun mimu olofio ti le Kunu mimu lọja, to jẹ oun lawọn eeyan n beere fun julọ ki Kọlẹra too de.

"Eroja protein ati fitami pọ ninu nnkan mimu ti a fi ofio ṣe, bẹẹ lawọn mi-in n lo fun ki ara wọn fi ji pepe nitori ibalopọ.

‘’Ti o ba po ofio pọ mọ dabinu, ohun ti a gbọ ni pe o maa ṣe aleekun agbara ibalopọ, ṣugbọn emi o ti i wadii debẹ yẹn ṣaa.

‘’Ṣugbọn ohun ti mo fẹran pupọ lara ofio ni pe o jẹ ọna kan lati ri eroja protein pupọ, bẹẹ lo si tun ni awọn eroja mi-in ti a n pe ni minira pẹlu fitamin ninu."

Bakan naa, Juliana Osakue to ti kẹkọọ nipa fifi ewe ati egbo ṣe iwosan, sọ pe ofio n ṣiṣẹ gidi teeyan ba lo o bo ṣe yẹ ko lo o fun iwosan.

Iya naa sọ pe paapaa labala aiṣede nibi ibalopọ ọkunrin ati obinrin. O ni ko si ni i ṣe eeyan ni jamba kankan rara lẹyin lilo naa ( Zero side effect).

Báwo lo ṣe lè ṣe ohun mímu pẹ̀lú òfìò?

Aworan ohun mimu ti wọn fi ofio ṣe

Oríṣun àwòrán, Getty image

Wọn ni bi o ba ti rẹ ofio rẹ sinu omi mọju, ti o fi agbọn ati dabinu si i, eyi to ku ni ki o lọ ọ lẹrọ.

Lẹyin eyi, fi asẹ sẹ ẹ lati yọ omi kuro lara fulufulu. O ti di mimu lẹyin eyi.

Awọn mi-in maa n fi ata ilẹ (ginger) si i lati jẹ ko ta lẹnu ko si ṣiṣẹ daadaa. Ṣugbọn awọn eeyan mi-in ki i fi ata ilẹ si tiwọn rara.

Ninu amọran Ọmọwe Olowofoyeku, o ni ki awọn ti ofio ko ba ba lara mu jinna si i, nitori awọn eeyan kan wa ti wọn maa n koju awọn ayipada lara wọn bi wọn ba jẹ nnkan kan ti ko ba wọn lara mu.

O ni ṣugbọn oun ko ri wahala kankan pẹlu mimu nnkan mimu ti wọn fi ofio ṣe . Afi awọn ti wọn maa n fi ṣuga pupọ ba aye nnkan mimu naa jẹ.

O ni eyi ko daa fawọn ti wọn ba ni itọ ṣuga, nitori dabinu to wa ninu Tiger nut ti ni ṣuga to pọ lara ni tiẹ tẹlẹ.

Àwọn àǹfààní tí òfìò lè ṣe fún ara rẹ

Aworan awọn ti wọn n ta ofio

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọmọwe Olowofoyeku ka awọn nnkan wọnyi bii anfaani to wa ninu ofio:

Gbígbógun ti àìlè ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ nírọ̀rùn

O maa n gbogun ti ai le ṣe igbọsẹ nirọrun nitori eroja protein ati fibre to wa ninu rẹ.

Akọsilẹ kan to wa lati ‘National Center for Biotechnology Information’ sọ pe ofio ni eroja fibre to pọ ju ti awọn ounjẹ mi-in lọ.

Iwadii fi han pe awọn ounjẹ ti wọn ba kun fun eroja fibre maa n dena jẹjẹrẹ ifun, aile ṣe igbọnsẹ daadaa, ara sisan asanju ati aisan ọkan.

Ìtọ Ṣúgà

Fun awọn eeyan ti wọn ni aisan itọ ṣuga, o daa ki wọn mu ohun mimu olofio tiwọn bẹẹ lai fi adun kankan si i.

Bẹẹ ni Olowofoyeku wi.

O ni iwe kan,’International Journal of Diabetes in Developing Countries’ ti wọn gbe jade ni 2015, ṣalaye pe o daa kawọn eeyan ti wọn ni itọ ṣuga oriṣi keji (type 2 diabetes) maa jẹ ofio, nitori o maa n ṣatunṣe si bi ṣuga yoo ṣe pọ to ninu ẹjẹ wọn.

Ofio tun ṣee rọpo miliiki bi Olowofoyeku ṣe ṣalaye.

‘’Ti o ba mu ohun mimu ti a fi ofio ṣe, inira to maa n ba awọn ẹlomi-in bi wọn ba mu miliki gangan ko ni i sọ ọ wo rara. "

‘’National Center for Biotechnology Information’’ naa sọ ninu ọrọ apilẹkọ wọn kan, pe ofio tun wulo fawọn ti wọn n ṣe ohun jijẹ bii burẹdi, ororo wa lara rẹ bi wọn ṣe wi, o si le di makaroni (tiger nut pasta).