Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Lori Ko ṣe e ma gbọ ọ ti ọsẹ yii a ṣe agbẹyẹwo bi eeyan 45,000 ṣe padanu ẹmi wọn sọwọ aisan to ni i ṣe pẹlu HIV/AIDS ni Naijiria lọdun 2023.
Àjọ tó ń rí sí àmójútó ààrùn kògbóògùn HIV/AIDS ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NACA ní èèyàn 75,000 ló kó ààrùn HIV ní Nàìjíríà lọ́dún 2023 nìkan.
Adarí àjọ NACA, Dókítà Temitope Ilori ló sọ èyí níbi ètò kan tí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìdènà HIV ṣe agbátẹrù rẹ̀ nílùú Abuja lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 2024.
Ilori ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àdínkù ti bá bí àwọn èèyàn ṣe ń kó ààrùn HIV síbẹ̀ ó ní ó pọn dandan láti ṣe àmúṣẹ àwọn àbá tí wọ́n dá níbi ìpàdé àpérò láti dènà HIV tí wọ́n yóò bà á fòpin sí ààrùn HIV/AIDS ní ọdún 2030.
Bákan náà ni a tún wo bí àìsàn kọ́lẹ́rà ṣe jẹ́ ohun tó ń kọ ìjọba Nàìjíríà lóminú ti wọn si ti da awọn ibudo silẹ lati maa mojuto iṣẹlẹ pajawiri lori kọlẹra