Ìjọba Oyo kéde ọjọ́ ìwúyè Olubadan tuntun

Gómìnà Seyi Makinde àti Ọba Owolabi Olakuleyin

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti buwọ́lu ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje, ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n máa gbé adé le Ọba Owolabi Olakuleyin bíi Olubadan tuntun.

Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Ọba Owolabi Olakuleyin tún máa gba ọ̀pá àṣẹ oyè rẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade ni Gomina Seyi Makinde ti kéde náà.

Oba Owolabi Olakuleyin
Oba Owolabi Olakuleyin

Oyelade nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo láti máa ṣe sùúrù pẹ̀lú ìjọba tó wà lóde pàápàá bí kò ṣe ti já wọn kulẹ̀ láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn.

Ó ní gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ àtàwọn ìwà míì táwọn èèyàn kan ń gbé kiri kò ní ṣi gómìnà Makinde lọ́kàn láti yẹ nídìí òótọ́ àti láti máa ṣe déédéé pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ Oyo.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo pàápàá àwọn olùgbé ìlú Ibadan láti fojú sọ́nà fún ayẹyẹ ìwúyè náà tó ń bọ̀ lọ́nà.

Ẹ ó rántí pé láti ìgbà tí Olubadan tó gbèsè, Oba Moshood Olalekan Balogun ti darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ ní oṣù Kẹta ni àwọn èèyàn ìlú Ibadan ti ń fojú sọ́nà kí Ọba Olakuleyin gorí ìtẹ́ àwọn babańlá rẹ̀.