Ọrọ̀ owó oṣù òṣìṣẹ́ bá ọ̀nà mìíràn yọ, NLC sọ̀kò ọ̀rọ̀ sáwọn gómìnà

Oríṣun àwòrán, NLC/FACEBOOK
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti korò ojú sí àwọn gómìnà ẹkùn gúúsù Nàìjíríà tí wọ́n ń bèèrè fún pé kí àwọn òṣìṣẹ́ fún gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àǹfàní láti dùnáádùrá pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ wọn láti fẹnukò lórí iye tí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan le san gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ.
NLC ní àìmọ̀kan ló ń dààmú àwọn gómìnà náà nítorí òfin ti wà lórí owó oṣù tó kéré jùlọ.
Igbákejì Ààrẹ NLC, Benjamin Anthony sọ fún BBC pé òfin wá káàkiri àgbáyé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ àti pé nígbà tí wọ́n bá ti gbé òfin kalẹ̀ lórí owó náà kò sí ẹ̀ka ìjọba kan tó ní ẹ̀tọ́ láti yipadà.
Benjamin Anthony wòye pé ìyà ńlá ni ìjọba fi ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà tí wọ́n bá wo bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe ti dà ní orílẹ̀ èdè yìí.
Ó ní ti ìjọba bá tẹnumọ pé ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta náírà (₦62,000) ni àwọn fẹ́ san gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ, èèlò ni wọn yóò máa fi ra epo nínú rẹ̀?
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn gómìnà náà nílò láti ronú nípa nǹkan tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú látàrí bí gbogbo nǹkan ṣe ti gbówó lórí léyìí tó fà á tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fi ń bèèrè fún ẹgbẹ̀rún àádọ́ta lé ní igba náírà (₦250,000).
“Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ aládàni sọ pé àwọn máa san ₦120,000, a sọ pé ₦250,000 là fẹ́.
“Tí ẹ bá wo iye tí àpò Ìrẹsì di báyìí, ẹ ma ri pé owó oṣù òṣìṣẹ́ kò tó ra ohunkóhun mọ́ lọ́jà.”
Benjamin Anthony ní Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni àwọn ń retí kó sọ̀rọ̀ lórí owó oṣù tuntun náà kí àwọn tó mọ ìgbésẹ̀ tó kàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́.
Ó ní ìwọ́de ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń bọ̀ lọ́nà láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lẹ́yìn tí àwọn gómìnà kan sọ pé àwọn kò lè san ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta náírà tí ìjọba àpapọ̀ ń sọ pé àwọn fẹ́ san.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kan bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, Nasiru Idris Kauran Gwandu ní òun ti ṣetán láti san iyekíye tí ìjọba àpapọ̀ bá ti buwọ́lù gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ.















