Biden, Trump ṣe ìtàkùrọ̀sọ l’Ámẹ́ríkà, wo àwọn irọ́ tí Donald Trump gbé kalẹ̀ níbẹ̀ àti ohun táwọn olólùfẹ́ Democratic Party ń sọ

Aworan Biden ati Trump nibi itakurọsọ

Eto ifigagbaga itakurọsọ itagbangba laarin oludije fun ipo aarẹ lorilẹede Amẹrika to waye laarin Aarẹ ana, Donald Trump ati Aarẹ to wa lori ipo lọwọ , Joe Biden waye lọjọbọ. Oniruuru itakurọsọ lo si ti jade lẹyin rẹ.

Bi awọn eeyan ṣe n sọ ti ijakulẹ Aarẹ Joe Biden ti wọn si n ni ọjọ ori rẹ ti n farahan ninu ihuwasi ati isọrọsi rẹ, lawọn miran n woye pe ọpọ aiṣootọ kun ọrọ Donald Trump, bẹbẹ lo si gbiyanju lati yẹra fun gbogbo ibeere ti wọn beere nipa ipa to ko ninu bi awọn ololufẹ rẹ kan ṣe kọlu ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika, Capitol Building lọdun 2021.

Lasiko itakurọsọ itagbangba naa, Aarẹ Joe Biden ni ọpọ inira pẹlu idahun rẹ. Eleyi si ti mu ki ọpọ maa wo o pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ọjọ ori rẹ ni o n faa. Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic Party kan gan tilẹ ti n beere lẹyin itakurọsọ naa pe ṣe o ṣeeṣe ki wọn rọpo Biden gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu ọhun.

Awọn ololufẹ Biden nibi eto rẹ

Awọn irọ wo ni Donald Trump pa lasiko itakurọsọ naa?

Aworan awọn aarẹ ilẹ Amẹrika lati ọdun 1969 pẹlu ọjọ ori wọn

Lootọ Donald Trump sọ ọpọlọpọ ọrọ pẹlu igboya lasiko itakurọsọ itagbangba naa ṣugbọn awọn irọ to pọ wa nibẹ.

“Oun lo jẹ gbese julọ ninu itan orilẹede wa”

  • Trump sọ ọ pe Joe Biden ti ko orilẹede Amẹrika wọ oko gbese ti ko si iru rẹ ri ninu itan. Amọṣa, awọn iwe akọsilẹ lati banki apapọ orilẹede Amẹrika fihan pe, lasiko iṣejọba Donald Trump gẹgẹbi aarẹ Amẹrika gan an ni gbese orilẹede naa ga julọ nigba ti gbese rẹ jẹ Tiriliọnu mẹta o le aadoje biliọnu owo dọla ($3.13trn). nigba ti yoo fi di ọdun 2023 labẹ iṣejọba Joe Biden gbese naa ti walẹ si triliọnu kan o le ẹẹdẹgbẹrin biliọnu dọla ($1.7trn).

“O fẹ ṣi aala ilẹ wa silẹ. O fẹ ki wọn ba orilẹede wa jẹ abi o fẹ lo awọn to n wọle gẹgẹ bi oludibo”

  • Ko si igba kankan ti Joe Biden buwọlu ṣiṣi aala ilẹ amẹrika silẹ. Nigba to gba ipo lọwọ Trump, Biden yi awọn ofin ti Trump gbe kalẹ lori eto wọlewọde, lara eyi ti eto kan wa to ni awọn to ba fẹ wọ orilẹede naa yoo kọkọ wa ni Mexico naa titi di igba ti igbẹjọ lori eto ati ṣe atipo wọn yoo fi waye. Amọ Biden ti gbe awọn igbesẹ kan to dena eyi.

“Iṣoro ti wọn ni ni pe wọn fẹ maa gba ẹmi lẹnu awọn ọmọde loṣu kẹjọ, oṣu kẹsan an, koda lasiko ibi wọn tabi lẹyin ti wọn ba bi wọn tan”

  • Trump sọ pe awọn ipinlẹ kan to wa labẹ iṣejọba ẹgbẹ oṣelu Democratic Party n faaye gba pipa awọn ọmọde lẹyin ibi wọn. Irọ nla ni eyi. Kaakiri gbogbo ipinlẹ aadọta to wa lorilẹede Amẹrika ni ofin ko ti fi aye gba ṣiṣekupa awọn ọmọde. Koda lawọn ipinlẹ ti ofin ti fi aye gba oyun ṣiṣẹ, o ṣoro lati ri ki wọn fi aye gba ki eeyan ṣẹ oyun to ba le ni ọsẹ mọkanlelogun- eyi ja si ida kan ninu ọgọrun iṣẹlẹ oyun ṣiṣẹ to n waye lorilẹede Amẹrika.