Ṣé lóòótọ́ ni àwọ́n jàǹdùkú kọlu Alabi Pasuma lóde eré ní Ikire?

Oríṣun àwòrán, Wasiu Alabi Pasuma/Facebook
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 ní ìròyìn kan gbòde pé, àwọn kan ṣe ìkọlù sí gbajúmọ̀ olórin Fuji, Wasiu Alabi Pasuma níbi tó ti lọ ṣeré ní Ikire, ìpínlẹ̀ Osun.
Nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára, ẹnìkan tí ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Paso ń sọ pé àwọn kan ṣe ìkọlù sáwọn ní Ikire.
Fídíò náà ṣàfihàn ọkọ̀ ńlá kan tí wọ́n ya Paso sí ara rẹ̀, tí gíláàsì rẹ̀ sì ṣàfihàn pé wọ́n ju nǹkan sára rẹ̀, tó lu ihò.
Ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò náà sọ pé "ọkọ̀ Paso rèé, wọn ṣe ìkọlù sí wa, wọ́n yìnbọn mọ́ wa àmọ́ Ọlọ́hun wà."
Ṣùgbọ́n Otunba Adekunle Abolade tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Dodoede tó ṣe agbátẹrù ìnáwó tí Pasuma ti lọ ṣeré náà ti wá ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ gan.
Àwọn tó fẹ́ fi agidi wọnú gbọ̀ngàn ayẹyẹ ló dá wàhálà sílẹ̀, wọn ò ṣèkọlù sí Pasuma - Dodoede

Oríṣun àwòrán, Wasiu Alabi Pasuma/Facebook
Iléeṣẹ́ ìròyìn OsunReporters nínú ìròyìn kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Ajé sọ pé, àwọn kàn sí Dodoede tó sì ṣàlàyé pé kìí ṣe Pasuma ni àwọn jàǹdùkú náà ṣe ìkọlù sí.
Ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Karùn-ún ni Pasuma lọ ṣeré níbi ayẹyẹ ìwúyè Olóyè Wasiu Ademola Abdulsalam Ajanaku gẹ́gẹ́ bí Mogbede ìlú Ikire.
Dodoede sọ pé àwọn tí wọ́n fi ìwé pè nìkan ló ní àǹfàní láti wọlé síbi ayẹyẹ náà gẹ́gẹ́ bí ètò, tí wọ́n sì gbọdọ̀ ṣàfihàn ìwé ìpè wọn fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà níbi ètò náà.
Ó ní àwọn jàǹdùkú kan tí wọ́n kò ní ìwé ìpè ayẹyẹ náà lọ́wọ́, tí wọ́n sì fẹ́ wọlé síbi ètò náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò sínú ọgbà ibi tí ayẹyẹ náà ti ń wáyé, tí òkò sì ba ọkọ̀ Pasuma.
"Kìí ṣe Pasuma tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù sí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń gbé lórí ayélujára.
"Àwọn tí kò ní ìwé ìpè láti wọnú gbọ̀ngàn tí ayẹyẹ ti ń wáyé ni wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní ju òkò sínú ilé tó sì ba ọkọ̀ Pasunma àti ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà níbẹ̀ lẹ́sẹ̀, kò sí nǹkan tó jọ mọ́ ìbọn yínyìn níbi ayẹyẹ náà."
Ó fi kun pé àwọn ta àtíbàbà síta ibi ayẹyẹ náà, èyí tó gba èrò tó tó 1,500, táwọn sì tún gbé ẹ̀rọ ayàwòrán tó ń ṣàfihàn gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú gbọ̀ngàn fáwọn tí kò ní ìwé láti wọ ilé àmọ́ kò tẹ́ àwọn kan lọ́rùn.
Dodoede tẹ̀síwájú pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ afurasí márùn-ún tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé ó wà lára àwọn jàǹdùkú tó ṣe ìkọlù níbi ayẹyẹ náà.
Ó ní àwọn afurasí náà wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá nílùú Osogbo, olú ìlú ìpínlẹ̀ Osun níbi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé Pasuma àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti padà sí ìlú Eko láyọ̀ àti àlááfíà àti pé kò sí nǹkankan tó ṣe wọ́n láti ibi ayẹyẹ náà.
Ó ní káwọn èèyàn kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn tó ń lọ lórí ayélujára pé wọ́n ṣe ìkọlù sí Pasuma àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.
Ta a ni Pasuma?

Oríṣun àwòrán, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma/Facebook
Ọ̀kan lára àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí iṣẹ́ orin Fuji ni Pasuma.
Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 1967 ni wọ́n bí Alhaji Wasiu Alabi Pasuma tí àwọn míì tún máa ń pè ní Paso.
Ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Eko ló gbé dàgbà pẹ̀lú ìyá rẹ̀, Alhaja Kubura Odetola tó máa ń pè ní ìyàwó Anọ́bì.
Ní ọdún 1984 ni Pasuma ní òun bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ orin sílẹ̀ lẹ́yìn tí òun gba ìmísí láti ara orin Wasiu Ayinde.
Ọdún 1993 ni Pasuma gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Recognition" jáde.
Lẹ́yìn ìgbà náà ló sì tún ti gbé àwọn orin tó lè ní ọgbọ̀n jáde.
Lágbolé Fuji, òdú ni Pasuma tí kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn olórin Fuji ló máa ń fẹ́ ṣe bí òun náà.
Onírúurú àmì ẹ̀yẹ ni Pasuma ti gbà nídìí iṣẹ́ orin Fuji.



























