Ẹgbẹ́ òṣiṣẹ́ ń bèèrè fún òpin òfin owó orí, pè fún àgb́éyẹ̀wò owó oṣù

Aworan Aarẹ Naijiria Bola Tinubu ati Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti kesi Aarẹ Bola Tinubu pe ki o jawọ ninu ofin owo ori to nfi ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin, ko si jẹ ki awọn araalu jiroro nipa ofin naa.

Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade ti aarẹ NLC, Joe Ajaero fi lede lati se ayajọ ọdun tuntun nibi ti wọn ki awọn araalu ku ọdun tuntun.

Ajaero ni o ṣe koko ki ijiroro waye lori ofin saaju ki ibuwọlu ofin nipa owo ori to waye.

"Lati safihan ijọba awarawa, a ni lati pese aye fun jiroro, ki a si fun awọn araalu ni anfani lati da si ọrọ.

"A wa n kesi ijọba ki wọn da ofin nipa owo ori eyi to wa ni iwaju ile igbimọ aṣofin agba bayii pada lati le ki awọn araalu ati awọn ti ọrọ kan yanayana rẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn ṣetan lati pese iranlọwọ lori ọrọ owo ori eyi ti yoo jẹ itẹwọgba lawujọ, to si tun mu alekun ba ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Ofin owo ori jẹ ọkan ninu ofin ti aarẹ Bola Tinubu ti gbe sita lati gba to ti di aarẹ lọdun 2023.

Ẹwẹ, ọpọ ẹnu lo ti n kun ofin naa, paapa lati apa ariwa Naijiria, awọn gomina ati bẹẹ lọ.

Nigba ti Aarẹ n sọrọ ninu ifọrọwerọ kan to se niluu Eko, Tinubu ni oun yoo ri pe ofin tuntun nipa owo ori ọhun wa si imusẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ tun pe fun agbeyẹwo owo oṣu lati sisẹ gẹgẹ bii moriya fun awọn oṣiṣẹ.

Ajaero ni o se koko ki ijororo nipa owo oṣu waye nitori inira ti awọn oṣiṣẹ n la kọja lasiko yii.

"Awọn ipenija ti a n la kọja gẹgẹ bii eeyan ni ko gbudọ mu wa mọlẹ. A ni lati wa agbara lati mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria si ilẹ ileri.

"Ko si agbara kankan ti yoo wa kuro ninu kudiẹkudiẹ to ba ọrọ Aje wa yii ṣugbọn ti a ba fọwọsowọpọ, a gbe orilẹede siwaju."