Mọ̀ nípa iye owó orí tí wà á máa san lórí owó oṣù rẹ

Aworan ontaja to n siro owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi a se n wọ ọdun tuntun, ijọba orilẹede Naijiria ti ṣalaye bi awọn araalu yoo se ma san owo ori paapa awọn oṣiṣẹ ijọba ati aladani.

Taiwo Oyedele, alaga igbimọ aarẹ to n ri si owo ori lo ṣalaye ọrọ nipa owo ori naa lori ikanni ayelujara rẹ.

Oyedele ni ọdun 2011 ni ijọba gbe ilana sisan owo ori tuntun sita, ṣugbọn nitori ọwọngogo, ọpọ awọn igbesẹ ijọba ni ko wa si imusẹ.

"Opọ awọn to n gba owo bi N400k loṣu ni wọn n san owo kanaa pẹlu awọn to n gba bi ogun milọnu loṣu,

"Owo ori yii n fa ọpọ ifasẹyin, ti ko si mu ilọsiwaju wa gẹgẹ bii erongba Ijoba."

Oyedele ni atunṣe ti ijọba mu ba owo ori lọwọ yii ni yoo wa ojutu si gtbogbo kudiẹkudiẹ nipa owo ori.

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Taiwo Oyedele

Se lootọ ni pe awọn oṣisẹ yoo san ọpọ owo ori?

Oyedele ṣapejuwe iroyin to n ja kiri pe awọn oṣiṣẹ yoo ọpọ owo ori labẹ ofin tuntun gẹgẹ ofege.

O tẹsiwaju pe oṣiṣẹ to ba n gba owo toto N1.7m tabi to kere jubẹ lọ yoo san owo ori to kere, ti awọn to si n gba owo oṣu to kere ju ni o ṣeese ki wọn ma san owo ori rara.

Igbesẹ yii ni yoo jẹ ki ida aadọrun oṣisẹ ni ẹka ijọba tabi aladani san owo ori to kereti awọn to n gba jubẹ lọ yoo san owo ori toto ida mẹdọgbọn iye owo ti wọn n pa.

"Fun eeyan to n gba to n gba bi ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira losu ko ni san owo owo ori ṣugbọn eeyan to n gba naira kan le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn yoo san owo ori ṣugbọn bayii gbogbo eyi ti ni iyanju labẹ ofin tuntun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nnkan to yẹ ko mọ nipa ofin owo ori tuntun

Nigba to n sọrọ niwaju awọn aṣofin, Taiwo Oyedele ni awọn ọlọla nikan ni ọrọ naa kan, ati pe ofin ọhun tun waye lasiko yii lati ṣe atunṣe si kudiẹ-kudiẹ to wa ninu bi ijọba ṣe n pin owo ori ti araalu n san.

Oyedele sọ pe "Abadofin mẹrin to ṣe koko ni igbimọ yii gbe wa eyii ti afojusun rẹ jẹ lati ṣe atunṣe si eto owo ori wa.

"Ofin naa fẹ ko gbogbo ofin owo ori si abẹ ofin kan ṣoṣo, ki a mu irọrun ba bi araalu yoo ṣe maa san owo ori ki a si yọ awọn to n pa owo kereje kuro.

"Abadofin naa yoo ṣamulo bi a o ṣe maa fi imọ ẹrọ gba owo ori ati bi gbigba rẹ yoo ṣe rọrun."