Ìdí tí àwọn iléeṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ṣe fẹ́ dáwọ́ iṣẹ́ dúró láwọn ibì kan lọ́dún tuntun

Àwòrán àwọn iléesẹ́ tóń pèsè ìbáranisọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, MTN/GLO/AIRTEL/9MOBILE

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà ti dúnkokò láti gbégi dínà iṣẹ́ wọn láwọn agbègbè kan ní Nàìjíríà tí àjọ to ń mójútó ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà, Nigeria Communications Commission (NCC) kò bá ṣe àtúngbéyẹ̀wò iye tí àwọn èèyàn ń san fún ìbánisọ̀rọ̀.

Àwọn iléeṣẹ́ náà lábẹ́ ẹgbẹ́ Association of Licensed Telecommunications Operators of Nigeria (ALTON) ló fi ìdúnkokò yìí léde lọ́jọ́ Ajé, ọgbọ̀njọ́, oṣù Kejìlá, ọdún 2024 nínú àtẹ̀jáde kan tí alága wọn, Onímọ̀-ẹ̀rọ Gbenga Adebayo, buwọ́lù.

Adebayo ní àtúngbéyẹ̀wò gbọ́dọ̀ wáyé lórí iye owó táwọn ń gbà fún ìbánisọ̀rọ̀ tí àwọn yóò bá máa tẹ̀síwajú láti máa rí ojúṣe àwọn ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà lásìkò yìí.

Ó ní tí ìgbésẹ̀ kankan kò bá wáyé lásìkò, ó ṣeéṣe kí àwọn àyípadà kan wáyé lọ́dún tó ń bọ̀, èyí tó le mú kí àwọn má le pèsè nẹ́tíwọ́ọ̀kì fáwọn agbègbè kan mọ́.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni àwọn máa ma já dànù lọ́sàn-án, tó sì lè ṣàkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé, ààbò, ìlera ati ẹ̀kọ́ nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ka yìí ló gbára lé ẹ̀ka ìbánisọ̀rọ̀ láti le fi ṣiṣẹ́.

Ó tẹ̀síwájú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpèníjà táwọn ń kojú yìí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wáyé àmọ́ àwọn ìlàkàkà àwọn nínú ọdún 2024 jẹ́ kí ìṣòro náà tún peléke si, tó sì lè mú àkóbá ńlá bá iṣẹ́ àwọn.

Adebayo tún ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ń lò láti fi ṣiṣẹ́ bíi iná mọ̀nàmọ́ná ni ó ti gbówó lórí àti pé ọ̀wọ́n gógó ń fa ìnira fáwọn gidi.

Ó ní síbẹ̀ iye tí àwọn ń já fún ìbánisọ̀rọ̀ kò lékún léyìí tó sì ń sọ àwọn iléeṣẹ́ sóko gbèsè.

Ó kọminú pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni àwọn ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti pèsè nẹ́tíwọọ̀kì nítorí àwọn mọ pàtàkì rẹ̀ sí ìgbáyégbádùn àwùjọ àmọ́ àwọn ìpèníjà táwọn ń kojú bayìí kò ní jẹ́ kí àwọn lè tẹ̀síwajú láti pèsè wọn mọ́.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà yìí, àyípadà ọ̀tun lè wáyé lọ́dún 2025 tí ìjọba bá tètè gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá.

Láìpẹ́ yìí ni àjọ NCC fi àtẹ̀jáde kan léde pé àwọn kò fun àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láṣe láti fi owó kun iye tí wọ́n yóò máa jà lọ́dún 2025 gẹ́gẹ́ bí àwọn ìroyìn kan ṣe ń gbe kiri.

Láti inú oṣù Kẹrin ọdún 2024, ni àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti ń pè fún àyípadà iye tí wọ́n ń jà àmọ́ tí wọn kò fún wọn láṣẹ.

Alága ALTON náà wà rọ ìjọba àpapọ̀ láti jíròrò pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lẹ́ka ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kí wọ́n le wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ọ̀rọ̀ náà.