Ìjọba Cross River gba iṣẹ́ lọ́wọ́ adarí ilé ẹ̀kọ́ méjìlá lórí ẹ̀sùn rìbá

Oríṣun àwòrán, Sir Benedict Ayade CON
Adari ile ẹkọ girama mejila ti gba ewe ẹ lọ gbele yin ni ipinlẹ Cross River, nigba ti wọn gbe awọn kan lati ile ẹkọ kan lọ si omiran.
Eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin bi ijọba ipinlẹ ọhun ṣe fẹsun riba kan awọn adari ile ẹkọ naa.
Kọmiṣọnna eto ẹkọ ipinlẹ ọhun, Ọjọgbọn Godwin Amanke lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan niluu Calabar.
O ni “A ti fun ọpọ adari ile ẹkọ ni iwe lati wa ṣalaye tẹnu wọn,
a ti gba iṣẹ lọwọ adari ile ẹkọ mejila, a ni ki mẹfa lọ rọkun nile nigba ti a gbe awọn mẹrindilogun lati ile ẹkọ kan lọ si omiran.”
O ni oun gbọ pe awọn adari ile ẹkọ n san owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ki wọn le gbe wọn lati ile ẹkọ ti wọn n fẹ.
Amanke sọ siwaju si pe ijọba mọ nipa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ile ẹkọ girama, awọn si ti bẹrẹ isẹ lori rẹ.
Nigba to n sọrọ lori awọn aṣeyọri rẹ gẹgẹ bii kọmiṣọna, Amanke sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣatunṣe awọn ile ẹkọ ti ogiri rẹ ti n wo.
O ni “To ba ṣeeṣe fun mi, mo maa fun awọn araalu ni ẹkọ ọfẹ, mo ṣe bẹẹ ri gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ.”
O pari ọrọ rẹ pe nnkan bii ẹgbẹrun kan olukọ tuntun ni ijọba naa n gba siṣẹ kaakiri ipinlẹ ọhun.












