Kí ló fàá tí àwọn olóṣèlú kò fi ń lo àwòrán Buhari lórí ìwé ìpolongo ìbò wọn?

Aarẹ Buhari n jùwó si awọn eeyan

Oríṣun àwòrán, Presidency nigeria

Bi ipolongo ibo fun idibo apapọ lorilẹede Naijiria lọdun 2023 ṣe n sun mọ dẹdẹ bayii, ara ohun kan ti eeyan lee ṣe akiyesi rẹ ni pe ọpọ awọn oludije.

Pàápàá lẹgbẹ oṣelu APC ni wọn ko lo aworan aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari pẹlu aworan tiwọn mọ ninu iwe ipolongo ibo alatẹka wọn.

Tẹlẹ, paapaa lasiko idibo apapọ ọdun 2015 ati 2019, ọpọ awọn oloṣelu lo n tẹ aworan Buhari pẹlu aworan ara wọn lati fi ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi olotitọ eeyan gẹgẹbi awọn naa ṣe fẹ ki awon eeyan o maa fi oju wo awọn pẹlu.

Amoṣa ọrọ naa da bi eyi ro ti yipada nitoripe nibi yoo wu to le lọ bayii ko daju pe o lee ri Oludije kankan ti yoo lo aworan aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari pẹlu aworan ara rẹ.

Pupọ ninu awọn oloselu to gbagbọ ninu ohun ti Aarẹ Buhari duro fun at’awọn eto ari ilana iṣejọba rẹ paapjulọ ni ipinlẹ Kano ni wọn ti dẹkun lilo aarẹ lati fi polongo fun awọn oludibo lati dibo fun wọn.

Aarẹ Buhari ati gomina Uzdinma ti ipinlẹ Imo n juwọ

Oríṣun àwòrán, Presidency Nigeria

Kini o n ṣẹlẹ ni Kano bayii?

Bi o tilẹ jẹ pe ipinlẹ Kano ni ipinlẹ ti wọn ti fẹran aarẹ Buhari julọ, nibayii o dabi ẹni pe nnkan ti yi pada, bi o ba lọ kaakiri ipinlẹ Kano bayii, aworan awọn ti o le ri ni aworan awọn oludije fun ipo aarẹ, gomina tabi ẹlomiran lẹgbẹ oṣelu APC leyan yoo ri bayii.

Awọn olugbe ipinlẹ naa kan sọ fun BBC pe iṣejọba aarẹ Buhari ti su awọn, idi niyi ti awọn ko fi tara si boya ẹni kan fi fọto aarẹ sara iwe ipolongo rẹ tabi ko fi sii.

Amọṣa o awọn olugbe ipinlẹ naa miran ṣi tun sọ fun BBC pe bo ti wu ko ri, ninu ẹrun, ninu ojo, awọn ko le dẹkun ati maa fẹran rẹ.

Wọn ni bi awọn ba fẹ gbe apoti ibo kankan, awọn yoo lo aworan aarẹ pọ mọ aworan tiwọn ni.

Ki lawọn onwoye ri si eyi?

Eeyan kan gbe iwe alakọle pẹlu aworan aarẹ Buhari lọwọ

Oríṣun àwòrán, AFP/getty images

Ọjọgbọn Kamilu Sani Fagge, to jẹ olukọni ni fasiti Bayero University to ba BBC sọrọ sọ pe ọrọ naa lee nii ṣe pẹlu awọn ijakulẹ atẹyinwa lẹyin ti Buhari ni ki wọn di gbogbo ibo ipele gbogbo fun ẹgbẹ oṣelu rẹ.

O ṣalaye pe, “ni igba kan ri, awọn eeyan kan maa n fi aworan aarẹ Muhammadu Buhari da aṣọ wọ nibi ti wọn fẹran rẹ de ti wọn si n dibo fun ẹnikẹni ti wọn ba mọ mọ ọ laifẹ mọ boya onitọhun kun oju iwọn tabi rara.

Aarẹ Buhari pẹlu awọn eekan kan ninu iṣejọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, presidency nigeria/ bayo omoboriowo

Amọ nisiyi ti aarẹ Buhari ko fi bẹ niyi mọ loju ọpọ, awọn oludije naa ti mọ pe bi awọn ba so ara wọn mọ ọ ko si anfani kankan to lee fun awọn.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ko fi bẹẹ fẹran Buhari mọ, awọn kan ṣi wa to fẹran rẹ bi iṣan ọrun.

Igba kan wa to jẹ wi pe lati kansilọ de gomina lo n fi aworan aarẹ Buhari ṣe ipolongo kaakiri awọn patako ipolongo ti awọn kan si n gbagbọ pe ẹnikẹni to ba sun mọ Buhari ẹni pipe ati olododo.