Surprised Birthday: Iléẹjọ́ pàṣẹ kí iléeṣẹ́ san $450, 000 owó ìtanràn fún òṣìṣẹ́ tí wọ́n fi tipátipá se ọjọ́ ìbí fún

Ami ajọyọ ọjọ ibi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ kan ni Kentucky ti dajọ fun arakunrin kan pe ki wọn san owo idalare ẹgbẹrun lọna irinwo ati aadọta dọla fun un.

Eyi ri bẹẹ lẹyin ti ileeṣẹ to n ba ṣiṣẹ ṣeto ajoyọ ọjọ ibi iyalẹnu fun un lainaani ikilọ to ṣe fun wọn pe o lee fa ipaya ati iporuru ọkan fun oun.

Arakunrin Kevin Berling ni ajọyọ ọjọ ibi naa ti wọn ṣe fun oun lọdun 2019 ni ileeṣẹ Gravity Diagnostics da ọpọ ipaya si ara oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ileesẹ naa dẹyẹsi oun nitori oun jẹ akanda ẹda.

Ileeṣẹ naa ni oun ko jẹbi ẹsun kankan o.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Ki lo mu ki olupẹjọ tako ajọyọ ọjọ ibi kanpa?

Ọgbẹni Berling pe ẹjọ ni agbegbe Kentucky Kento ninu eyi to ti salaye pe oun ti sọ fun ọga oun pe ki wọn maa ṣe ajọyọ ọjọ ibi fun oun ni ibi iṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe fun awon oṣiṣẹ wọn gbogbo.

Berling ni igbesẹ naa le e da ipaya ati iporuru ọkan si oun lara leyi ti yoo mu ki oun ranti awọn iṣẹlẹ igba ewe ti oun ko fẹ ranti rara.

Lainaani arọwa ogbẹni Berling, ileeṣẹ naa ṣe ajọyọ iyalẹnu fun un ni oṣu kẹjọ ọdun 2019 eyi to fa iporuru ọkan fun un, to si fi ibi apejẹ naa silẹ lai ba wọn pari.

Olupẹjọ ni wọn fi ẹsun kan oun pe oun da okuta sinu iyọ idunnu awọn akẹgbẹ oun:

Igbẹjọ naa tun salaye siwaju sii pe ṣe ni awọn ara ibi iṣẹ rẹ tun bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹ lu u pẹlu oniruuru ọrọ alufansa nibi ipade kan to waye lọjọ keji nileesẹ naa.

O ni wọn fi ẹsun kan oun pe o "da okuta sinu iyọ idunnu awọn akẹgbẹ rẹ."

O ni ipade yii lo tun wa fa iṣẹlẹ ipaya keji sii lọkan lẹyin eyii ti ileeṣẹ naa wa daa pada sile fun iyoku akoko iṣẹ lọjọ kẹjọ ati ikẹsan ọdun 2019.

Ni ójọ kọkanla oṣu kẹjọ ni ileeṣẹ Gravity Diagnostics le e lẹnu iṣẹ lori awawi nipa aabo lẹnu iṣẹ.

Ẹjọ to pe ni ileeṣẹ naa dẹyẹsi arakunrin naa ni nitori alaabọ ara ni ati pe wọn mọọmọ hu iwa naa ni lẹyin to ti kọkọ parọwa si wọn.

Lẹyin igbẹjọ ọjọ meji lopin oṣu kẹta, ileẹjọ paṣẹ ki wọn san ẹgbẹrun lọna irinwo ati aadọta dọla ($450,000) fun olupẹjọ naa.

Ninu owo itanran naa ni ẹgbẹrun lọna ọdunrun jẹ owo gba naa binu fun iporuru ọkan, ẹgbẹrun lọna aadọjọ ($150,000) jẹ owo inawo fun igbẹjọ naa.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Ki ni awọn agbẹjọro igun mejeeji sọ lẹyin idajọ?

BBC ti kan si ileeṣẹ Gravity Diagnostics ati agbẹjọro wọn lati gbọ tẹnu wọn lori igbẹjọ naa.

Ọga agba ileeṣẹ naa, Julie Brazil sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan NKY pe ileesẹ naa ṣi duro lori igbesẹ rẹ lati le ọgbẹni Berling lẹnu iṣẹ.

Brazil salaye pe nitori ihuwasi rẹ tako ilakalẹ ileeṣẹ naa lori iwa ipa lẹnu iṣẹ ati pe awọn n gbero pipe ẹjọ kotẹmilọrun laipẹ.

Agbẹjọro fun ọgbẹni Berling, Tony Bucher fi to BBC leti pe ko si ẹri kankan to fihan pe arakunrin naa da wahala si oṣiṣẹ ileeṣẹ naa kankan lọrun, to le mu ki ileeṣẹ naa yọ ọ niṣẹ.

Akojọpọ iwadii lati ajọ iwadii nipa aisan ọpọlọ, National Alliance on Mental Illness fihan pe ogoji milionu awọn ọmọ ilẹ Amẹrika, to duro fun ida ogun ninu ọgọrun iye awọn eeyan orilẹede naa, lo ni aisan ipaya ati iporuru ọkan.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà