Rayan: Gbogbo ìgbìyànjú láti yọ Rayan láàyè láti ọjọ́ mẹ́rin tó ti kó sínú kàǹga jásí pàbó

Awọn obi Rayan laarin awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọmọ ọdún márùn-ún, Rayan tó kó sí kàǹga láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní orílẹ̀ èdè Morocco ti jáde láyé pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan ni wọ́n ti kéde ìkú ọmọ náà lẹ́yìn tí wọ́n yọ ọ́ tán ninu kanga.

Inú fo, àyà fo ní àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà wà láti ìgbà tí ọmọ náà ti kó sínú kàǹga, tí inú rẹ̀ jìn tó mítà méjìlélọ́gbọ̀n.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láti yọ ọmọ náà pàápàá ń bẹ̀rù kí ilẹ̀ má lọ ya lé ọmọ náà lórí.

Ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni wọ́n tó rí Rayan yọ, tí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń dùn láìmọ̀ pé òkú rẹ̀ ni wọ́n rí yọ.

Awọn adoola ẹmi gbẹ iho to jin sẹba kanga naa

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìdùnú àwọn ènìyàn di ìbànújẹ́ lẹ́yìn àtẹ̀jáde kan láti ààfin Ọba orílẹ̀èdè, Ọba Mohammed kẹrin, eyi to kéde ikú ọmọ náà.

Onírúurú ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ni àwọn ènìyàn ń fi sórí ẹ̀rọ ayélujára láti fi kọrin arò lẹ́yìn iku ọmọ náà.

Ọba Mohammed ní ó jẹ́ ọgbẹ́ ọkàn pé gbogbo ìgbìyànjú láti yọ Rayan já sí pàbó.

Bákan náà ni Ààrẹ ilẹ̀ Faransé, Emmanuel Macron bá àwọn òbí Rayan kẹ́dùn lórí ikú ọmọ wọn àti orílẹ̀ èdè Morocco lápapọ̀.

Báwo ni Rayan ṣe dé inú kàǹga?

Bàbá Rayan ní ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ọ̀hún wáyé lásìkò tí òun ń ṣe àtúnṣe sí kàǹga náà ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní kété tí òun gbójú kúrò lára ọmọ náà.

Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun yìí sì ni àwọn ẹ̀ṣọ́ adóòlà ẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti yọ ọmọ náà ní ìlú Tamorot.

Ní ọjọ́bọ̀ ni ẹ̀rọ ayàwòrán ṣàfihàn rẹ̀ pé Rayan ṣì ń mí, tí wọ́n sì fi oúnjẹ àti afẹ́fẹ́ "oxygen" ráńṣẹ sí i láti máa fí mí.

Sùgbọ́n wọn kò mọ̀ bóyá ó rí àwọn nǹkan náà lò.