Child Trafficking: Wo bí ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá ṣé tẹ Baba tó fẹ lù ọmọ rẹ̀ ní gbànjo $1000

Oríṣun àwòrán, Thinkstock
Ọrọ naa jọ bi fiimu agbelewo ṣugbọn kii ṣe arosọ rara ati rara.
Arakunrin kan to fẹ lu ọmọ rẹ ta ni gbanjo ti ko si panpẹ awọn ọlọpaa ni Liberia.
Alupupu ti eeyan kan gbe fun n ti wọn ji gbe mọ ọ lọwọ lo fẹ fi owo ra to fi fẹ ta ọmọ rẹ.
Awọn ọlọpaa Liberia ni awọn ti fẹsun igbiyanju lati ta ọmọ ọdun mẹwaa rẹ kan arakunrin yi.
Ẹni ọdun mọkandilọgbọn nii ṣe, orileede Sierra Leone lo si ti wa.
Lẹyin ti wọn mu u, ọlọpaa to n ṣe iwadii ọrọ naa ni Monrovia sọ pe o loun nilo ẹgbẹrun kan dọla lati fi ra ọkada ọrẹ rẹ ti awọn kan ji gbe mọ lọwọ.
O ni awọn eeyan sọ fun oun pe ọna toun le ri fi ko owo yi jọ ni koun gbe ọmọ naa lati Sierra Leone lọ si Monrovia.
Ibẹ lawọn eeyan sọ fun un pe o ṣeese ki o ri eeyan ti yoo ra ọmọ naa ni kiakia.
Loṣu Kejila ni wọn bẹrẹ si ni pete ọrọ yi pẹlu ọkunrin alarobọ kan to n ṣowo rira eeyan.
Lasiko idunadura yi, wọn a si maa pe ọmọde naa ni adiẹ ki awọn eeyan ma baa mọ pe eeyan ni wọn fẹ ta.
Toun ti gbogbo ọgbọn wọn, awọn ọtẹlẹmuyẹ pada mu baba ọmọ yi bo tiṣe fẹ lọ pade ẹni to fẹ ta mọ naa fun.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin oju opo ayelujara Liberia kan Global News Network ti ṣe sọ, ọmọ naa ti wa ni ọdọ awọn ileeṣẹ ijọba to n tọju awọn ọmọde.
Iṣẹlẹ fifi ọmọ ṣowo jẹ eleyi ti o wọpọ ni iwọ oorun Afrika.
Pupọ awọn ọmọde ti wọn ba ta wọnu oko ẹru kii ni anfaani latiba mọlẹbi wọn sọrọ mọ.
Lọpọ igba ni wọn a maa fi wọn ṣe iṣẹ bi akura ti awọn mii a si maa ṣe ọmọ ọdọ.
















