ICPC vs Kashamu: Irọ́ ni ICPC ń pa mọ́ Kashamu lórí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ áńbúlàǹsì àti ẹ̀rọ amúnáwá

Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, @SenatorBurujiKashamu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Irọ ni ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ, ICPC n pa mọ Sẹnẹtọ Buruji Kashamu lori ọrọ pe wọn fipa gba ọkọ anbulansi mẹta ati ẹrọ amunawa kan ni ọfdiisi rẹ niluu Ijebu Ode.

Oludamọran fun Sẹnẹtọ Kashamu lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Austin Oniyokor lo ṣalaye ọrọ yii fun ileeṣẹ BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ lori aago lọjọ Ẹti.

Agbẹnusọ fun ajọ ICPC, Rasheedat Okoduwa lo kọkọ ṣalaye ninu iroyin kan tawọn iwe iroyin gbe jade pe, awọn anbulansi ati ẹrọ amunawa naa jẹ iṣẹ iriju rẹ lẹkun Ila oorun ipinlẹ Ogun ti wọn ti dibo yan an.

Okoduwa ni miliọnu mẹfa naira ni ọkọ anbulansi kọọkan naa to yẹ ki Sẹnẹtọ Kashamu fi ṣọwọ sawọn Ile Iwosan to wa ni Obada ati Oke Sopin ni ijọba ibilẹ Ijebu East ati Ile Iwosan to wa ni Ogijo ni ijọba ibilẹ Sagamu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Okoduwa sọ di mimọ pe ajọ ICPC gbe igbesẹ yii lẹyin ti ara ilu kan tawọn lolobo nipa awọn ọkọ ati ẹrọ amunawa ọhun.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ṣugbọn oludamọran Sẹnẹtọ Kashamu lori ọrọ iroyin sọ pe igbesẹ ajọ ICPC jẹ iyalẹnu nitori Sẹnẹtọ Kashamu fun ra rẹ fi to ajọ naa leti pe Ọgbẹni Onadeko Onamusi to gbe iṣẹ naa fun ra ọkọ anbulansi ti ko dara to.

O ṣalaye siwaju si pe ajọ ICPC gbe Onamusi lọ sile ẹjọ lori ọrọ, bakan naa ni Sẹnẹtọ Kashamu fun un ni iwe gbele ẹ.

Ọgbẹni Oniyokor ṣalaye pe awọn ọkọ yii ati ẹrọ amunawa lo duro bi ẹri niwọn igba ti ọrọ naa si wa nileejọ.