2023 Elections: Ẹ ma ṣe dári ọmọ Yorùbá láti dìbò fún olóṣèlú kankan- Obasanjọ sọ fún Ooni Ife

Oríṣun àwòrán, Ooni/palace
Ààrẹ aná lórílèdè Nàìjíríà Olusegun Obasanjo ti gba Ọ̀ọ̀ni Ile-Ife, Ọba Enitan Adeyeye, Ogunwusi nimọran láti sọra ṣe o bi ètò ìdìbò ṣe n wolé bọ̀ lọ́dún 2023.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú ni yóò wá pé ki orí adé gbárúkù tì wọ́n, sùgbọ́n o sàn láti kàn gba àdúra fún wọn ki wọ́n máa bá ti wọn lọ.
Obasanjọ sọ èyí níbi ayẹyẹ ti Ọọni ṣe láti fún ọ̀gá àgbà ilé isẹ IITA Nteranya Sangina àti ìyàwó rẹ̀ Charlotte lóye Ààrẹ àti Yèyé Ààrẹ Afurugbin-Ọ̀la ilẹ̀ Yorùbá.
- Èsù ló ti mi láti san #2,650 fun owó mótò "Camry Muscle"- Afurasí
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
- Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀
- Irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kò níì tètè rí owó oṣù Kejìlá gbà
Ètò náà tó wáyé ni ààfìn Ọba Ogunwusi ni Ọbasanjo ti ṣàlàyé pé Ọ̀ọ̀ni gẹ́gẹ́ bi bàbá sí gbogbo ara ilú, àwọn olóṣèlú yóò wá pé ki orí àdé gbárúkù ti àwọn, sùgbọ́n nǹkan ti o tọ̀nà jùlọ ni pé kí o gbàdúra fún wọn ki wọ́n máá lọ.
"Ó nígbogbo ọmọ Káàrọ̀-òò-jííre ni gbogbo ibi ti wọ́n bá wà, wọ́n yóò wá láti bá Ọ̀ọ̀ni. Èyí di danadan nitóri ẹ̀yin ni bàbá wọn. Gẹ́gẹ́ bí Obasanjo ṣe sọ."
"Èyí kéyìí nínú wọn tó bá ni òún fẹ́ ṣe òṣèlú, kàn gbàdúrà fún wọn ki wọ́n máa lọ" Ẹnikẹ́ni tó bá wá tó ni òún fk du ipò ààrẹ Nàìjíríà, gbàdúrà fún kí o máa lọ.
"Má ṣe darí ọmọ Yorùbá kankan pé ẹni báyìí ni kí wọ́n dìbò fún, nítórí gbogbo wa kò lé máá lọ kí a korí sí ibìkan náà, èyí sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àmúṣagbára wa gẹ́gẹ́ bi ọmọ Yorùbá."
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáájú ni Ọ̀ọ̀ni Ilé-Ife ti gbóríyìn fún Sanginga to jẹ́ ọmọ oríléde Congo fún iṣẹ́ takùntakùn tó n ṣe fún ìdàgbàsóké ètò ọ̀gbìn nílẹ̀ Afirika.
" Inú mi dùn fún àwọn àṣeyọrí rẹ gẹ́gẹ́ bi ọmọ tòòtọ́ nílẹ̀ Afirika. O tí n ṣe gbogbo nkan tó ń ṣe láti ri pé òunjẹ́ wà lọ́pọ̀ yanturu lágbáyé."















