Wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí-Oluremi SAN
Oluremi Akintola Samuel nínú àlàyé rẹ̀ fún BBC pé, iṣẹ́ alága ti oun ń ṣe báyìí jẹ́ ọ̀nà láti di àlàfo tó wà láàrín àwọn àgbàlàgbà àti ọmọdé.
Nínú àlàyé rẹ̀, ó ni iṣẹ́ alága ìdúró àti ìjòkó ló si jẹ́ nǹkan gboogi to n di iṣe àti àsà Yoùbá mu ni òde òní.
Ìyáàfín Oluremi ni rọ gbogbo àwọln ọ̀dọ́ tó ń pinu láti ṣe iṣẹ́ alága láti ni ìfàrada kí wan si ma fi ojú àsà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá gbolẹ̀.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun dóòlà ọmọ ọdún méje tí alágbàtọ́ rẹ̀ n fìyà jẹ
- Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀
- Sunday Ìgbòho Yóò Padà Sílé Láyọ̀ àti Àlááfíà- Akeredolu
- Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko
"Ìdí tí mo fi sọ pé inú oyún ni mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága ni pé, Iṣẹ́ ti màmá mi ń ṣe ni ti mo si ti ń tẹ̀lé wọn lọ ẹnu iṣk láti ìgbà ti mo ti wa nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bọẹ̀rẹ̀."
Arabìnrin náà tó ni òun ti fẹ́ pé ogún ọdún lẹ́nu iṣẹ́ alága yìí ṣàlàyé ìrírí rẹ̀ ni ìgbà akakọ́ to gbá iṣẹ́ alága.

Ó ní nítorí pé òun jẹ́ ọmọdé, ẹni to bá òun gba isẹ́ náà ni kí on má jẹ́wọ́ fún àwọn tó ni iṣẹ́ pé òun ni yóò ṣe alága.
Ni báyìí Olurẹmi SAN ti di ilúmọ̀ọ̀ká Alága idúró nílé àti lẹ́yìn odi.