Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ni àwọn kò ní dásí ẹjọ́ adájọ́ Onnoghen ní CCT

Adájọ́ àgbà Onnoghen

Oríṣun àwòrán, OAL.LAW

Àkọlé àwòrán, Adájọ́ àgbà Onnoghen

Ijọba apapọ Naijiria ti sọ pe awọn ko ni ero lati yọ adajọ agba,Walter Onnoghen nípò.

Ninu atẹjade kan ti Femi Adeshina fi sita lọjọ abamẹta o salaye pe ''ko si ootọ ninu iroyin naa ti o tun sọ pe ijọba n gbero lati we ọrọ mọ awọn adajọ mẹta kan lọrun.''

Adeshina sọ pe iṣẹ ọwọ agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu, Coalition of United Political Parties (CUPP) ni iroyin naa eleyi to ni wọn fẹ fi da wahala silẹ saaju idibo apapọ to n bọ lọna.

''A ri wi pe iwadi ti ajọ to nrisi ihuwasi awọn osisẹ ọba atawọn to dipo asẹ mu,CCB n ṣe lori adajọ agba yi n lọ ni irọwọrọsẹ ti ijọba apapọ ko si ni erongba lati toju bọ igbesẹ naa''

Lẹnu ọjọ mẹta ti iroyin lu sita pe ijọba apapọ fẹ gbe Adajọ agba orilẹede Naijiria, Walter Onnoghen lọ si waju ile ẹjọ to n gbo ẹsun aṣemaṣe awọn to di ipo ilu mu, CCT, iriwisi ọtọọtọ lo ti n tele.

Ohun to jọ wi pe ijọba n fesi si nipa ọrọ to wa nileyi ni iroyin kan ti awọn iwe iroyin Naijiria gbe jade pe ijọba apapọ pe fun ki ile ẹjọ to n gbọ ẹsun awọn to di ipo nla mu lawujọ, CCT yọ adajọ agba Naijiria, adajọ Walter Onnoghen gẹgẹ bi adajọ agba ati alaga igbimọ awọn amofin Naijiria.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ ninu iroyin naa, awọn eeyan meji kan Musa Ibrahim ati Fatima Danjuma Ali ni wọn lo fiwe ipẹjọ sile ni iwaju ile ẹjọ CCT ni orukọ amofin agba orileede Naijiria lọjọbọ.

Igbesẹ yii gẹgẹ bi iwe ipẹjọ naa ti ṣe sọ, wa lati ri wi pe Onnoghen ko jẹ adajọ ninu igbẹjọ ara rẹ ati pe ẹni to kan lẹyin rẹ, adajọ Ibrahim Muhammad ni ko dele titi di igba ti ipinu gboogi yoo yọju.

Olupẹjọ ni ki ile ẹjọ jẹ ki aarẹ Muhammadu Buhari darukọ ẹni o tun kan lori aga lọga lọga gẹgẹbi adele adajọ agba ati alaga igbimọ awọn amofin Naijiria.

Ijọba ni awọn o kan dede maa sọ eyi ṣugbọn ohun to wa ninu iwe ofin ni awọn n tẹle.

Ẹwẹ, wọn wa rọ ile ẹjọ naa lati fi aṣẹ sita pe ki olujẹjọ naa yẹra gẹgẹ bi adaj agba Naijiria ati gẹgẹ bi alaga igbimọ awọn amọfin Naijiria lori ẹsun pe o ta ko ofin.

Igbesẹ ọtun yii lori ọrọ Walter Onnoghen waye lọjọ aje lẹyin ti ile ẹjọ to ni ṣe pẹlu ile iṣẹ nilu Abuja kọ lati jẹ ki alaga ile ẹjọ CCT, Danladi Umar, adajọ agba patapata, ile iṣẹ to n ri si ọrọ awọn to di ipo nla mu lawujọ yọ Onnoghen.

Àkọlé fídíò, Woli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika