AFCON 2021: Ajọ CAF kéde pé òun yóò ṣàmúlò ẹ̀rọ ayàwòrán VAR ní ìdíjé nàá ní Cameroon

Fídíò aṣèrànwọ́ rẹfẹrí (VAR)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igba akọkọ niyii ti wọn o lo VAR fun gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ni idije Africa Cup of Nations

Àjọ tó ń mójútó eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá nílẹ̀ Adúláwọ̀ (CAF) ti ní ẹ̀rọ ayàwòrán tí àwọn alamojuto idije ma n lo lati tọpinpin ifẹsẹwọnsẹ (VAR) ni yóò jẹ́ lílò ní gbogbo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjìléláàdọ́ta tí wọn yóò gbà á níbi ìdíje AFCON 2021.

Ó kú ìpele méjì tí ìdìje yóò parí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ síní ṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí níbi ìdíje AFCON 2019 tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Egypt.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ CAF ní ṣíṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí yóò jẹ́ ọ̀nà láti mú kí àwọn olùdárí ìdíje bọ̀ọ̀lù ní Afrika bẹ́gbẹ́ pé ní àgbáyé.

Adárí ayò mẹ́rìnlélógún, igbákejì mọ́kànlélọ́gbọ̀n àti ẹ̀rọ VAR mẹ́jọ láti orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógójì.

Obìnrin mẹ́rin ló wà lára awọn adárí ayò nàá.

Àwọn òṣìṣẹ́ méjì láti àjọ Caribbean àti Àríwá àti Ààrin gbùngùn Amẹ́ríkà yóò kópa.

Ẹni tó bá gba ipò kìíní nínú ìdíje yìí yóò gba mílíọ̀nù márùn-ún Dọ́là èyí tó fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé sí ti ọdún 2019.

Orílẹ̀-èdè tó bá ṣe ipò kejì àti ìkẹta yóò gba mílíọ̀nù méjì lé ẹ̀gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rinDọ́là.

Àwọn tó dé ipele sẹ̀mí fainà àti kúọ́tà fainà yóò gba mílíọ̀nù méjì lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Dọ́là àti mílíọ̀nù kan lé ẹ̀gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin.

Ọjọ́ Àìkú ní ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Cameroon àti Burkina Faso ní aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.