Alec Baldwin, òṣèrè sinimá, kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn fún yínyin ìbọn lásìkò tí wọ́n ń ya sinimá 'Rust'

Alec Baldwin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn adájọ́ kan ní New Mexico ti fẹ̀sùn àìmọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn tuntun kan òṣèré Alec Baldwin lórí bí wọ́n ṣe ṣiná ìbọn bolẹ̀ nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àgbà òṣèré náà ni wọ́n dànù nínú oṣù Kẹrin ọdún tó kọjá, lẹ́yìn tó ku ọ̀sẹ̀ méjì tó yẹ kí ìgbẹ́jọ́ ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀.

Àwọn olùwádìí tún ti fi àwọn ẹ̀rí tuntun lórí ohun ìjà tí wọ́n lò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà síta.

Àwọn agbejọ́rò Baldwin sọ fún BBC pé àwọn ṣetán láti pàdé nílé ẹjọ́.

Baldwin, ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin, ló ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe ń yìbọn Colt. 45 kí wọ́n tó ya fíìmù Rust ní ẹ̀gbẹ́ Santa Fe nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Àmọ́ ìbọn yínyìn náà bọ́ sódì bí ó ṣe lọ ba ayàwòrán ẹni ọdún méjìlélógójì, Halyna Hutchins.

Halyna Hutchins pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, tí adarí eré, Joel Souza sì farapa níbi àṣìta ìbọn náà.

Òṣèré náà ní òun kò yìnbọn náà àti pé òun kò jẹ̀bi ikú Hutchins nítorí òun kò mọ̀ pé ọta ìbọn wà nínú ìbọn náà nítorí kò yẹ kí wọ́n mú ọta ìbọn wá sí ibi tí wọ́n ti ń ya fíìmù.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àmọ́ àwọn olùpẹjọ́ ní New Mexico nínú oṣù Kẹwàá ní àwọn ti ní kí wọ́n ṣe àtúnṣe ìbọn ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n ti bà á jẹ́ nígbà ìwádìí FBI.

Wọ́n ní ìwádìí náà fi hàn pé bí kò bá ṣe pé wọ́n yìnbọn náà ni, ọta rẹ̀ kò lè jáde láti ṣọṣẹ́ tó wáyé nígbà náà.

Ẹ̀rí tuntun yìí ni wọ́n gbé síwájú àwọn Adájọ́ ẹlẹ́ni méjìlá lọ́jọ́bọ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn mẹ́jọ, ó kéré tán, ló gbọ́dọ̀ fẹnukò pé kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbé dìde, kí ìgbẹ́jọ́ mìíràn tó lè bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀.

Ẹ̀sùn tuntun tí wọ́n gbé dìde lọ́jọ́ Ẹtì ni wọ́n ti fẹ̀sùn kàn pé ó ṣeéṣe pé Baldwin kò mójútó lílo ìbọn bó ṣe yẹ tàbí pé kò ka ààbò àwọn yòókù rẹ̀ kún.

Àwọn olùpẹjọ́ ní ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀sùn yìí ni Baldwin máa kojú àti pé tó bá jẹ̀bi, ó ṣeéṣe kó lò tó ọdún kan àbọ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Agbejọ́rò tó ń ṣojú ẹbí olóògbé Hutchins ní àwọn ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ náà máa wáyé.

Agbejọ́rò ẹbí Hutchins, Gloria Allred ní àwọn oníbàárà òun fẹ́ mọ òótọ́ nípa nǹkan tó ṣẹlẹ̀ gangan lọ́jọ́ tí ìbọn ba Halyna Hutchins tó sì gbabẹ̀ kú.

Ibi ti ere sise naa ti n waye

Baldwin - ẹni tó ní ikú Hutchins jẹ́ ìbànújẹ́ tó sì bá òun lójijì - ní láti ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni òun kò ti rí iṣẹ́ òṣèré gbà mọ́.

Ẹ̀sùn tuntun tí wọ́n kà si Baldwin lọ́rùn yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ̀sùn ìpànìyàn kàn án àmọ́ tí wọ́n da ẹjọ́ náà nù látara àwọn ìpèníjà kan tó wáyé látọwọ́ àwọn agbejọ́rò rẹ̀, tí àwọn olùpẹjọ́ sì yọwọ́ lórí ẹjọ́ náà.

Àwọn olùpẹjọ́ tuntun da ẹjọ́ náà nù nínú oṣù Kẹrin ọdún 2023 pẹ̀lú ẹ̀rí pé ìbọn náà lè ṣe iṣẹ́ yínyin ara rẹ̀.

Hannah Gutierrez-Reed, tó wà ní ẹ̀ka àwọn nǹkan ìjà ogun níbi ìṣeré náà yóò kojú ìgbẹ́jọ́ tirẹ̀ ní oṣù tó ń bọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn tí wọ́n fi kan òun.

Dave Halls tó wà nídìí ètò ààbò gẹ́gẹ́ bí igbákejì adarí eré náà bẹ̀bẹ̀ pé òun kò jẹ̀bi.

Nínú oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni wọ́n parí eré Rust, nígbà tí àwọn tó ń ṣe fíìmù náà fẹnukò láti parí rẹ̀ ní ìrántí Hutchins àmọ́ wọn ò tíì máa tà á.

Ọkọ Hutchins Mathew àti ọmọ rẹ̀ tó wà ní ọdún mẹ́sàn-án lásìkò tí ìyá rẹ̀ jáde láyé, ni wọn yóò pín níbi èrè tí wọ́n bá pa nínú eré ọ̀hún.