Wo iye ìgbà tí ariwo ti ta pé àgbà òṣèré Olu Jacobs kú láàrin ọdún mẹ́rin

Aworan Olu Jacobs

Oríṣun àwòrán, Olu Jacobs/Instagram

Awaye ma ku kan ko si, ọrun nikan ni are ma bọ, bo pẹ bo ya gbogbo eeyan naa lo maa pada tẹri gbaṣọ.

Amọ, kikede iku eeyan nigba ti ẹni naa ṣi wa laaye kii ṣe nnkan awada rara nilẹ Yoruba.

Eyi lo sẹlẹ si agba oṣere Olu Jacobs tawọn eeyan kan ti n kede iku rẹ loorekoore lati bi ọdun mẹrin bayii nigba to ṣi wa laaye.

L'ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan maa n kede nnkan toju wọn ko to lori ayelujara lai ṣe iṣẹ iwadii to kuna.

Wọnyi ni iye igba ti iroyin ti jade pe Olu Jacobs jade laye nigba to ṣi wa laaye:

Iroyin ofege jade lọdun 2020 pe Olu Jacobs jade laye

Irọlẹ Ọjọru ọjọ kẹwaa oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni ariwo ta pe gbajugbaja osere tiata, Olu Jacobs, ti jade laye.

Igba keji niyi ni aarin osu kan ti ikede yoo waye pe ilumọọka osere tiata naa papoda, bẹẹ ni ọpọ eeyan to si gbọ ikede yii lo ka ọwọ sori pe ẹni re lọ.

Ṣugbọn iwadii BBC Yoruba ti fihan pe ahesọ ọrọ ati irọ nla to jinna si ootọ ni ikede naa, nitori Olu Jacobs si wa laaye, to n mi loke eepẹ.

Nigba to n fidi otitọ ọrọ mulẹ nipa ipo ti ọkọ rẹ wa, Joke Silva, to tun n jẹ Joke Jacobs, tii ṣe aya oṣere tiata naa ni ko ko ko bii okuta ni ara ọkọ oun le, ko si si iku kankan loju rẹ.

"Ko si ohun to ṣe ọkọ mi, koda, ó ń palẹ mọ lọwọ bayii lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin to de ile aye losu keje to n bọ, bẹẹ ni ẹnu ya awọn nigba ti ọpọ eeyan n beere pe ki lo ṣe ọkọ òun."

Joke Jacobs wa fi ọkan awọn ololufẹ wọn balẹ pe ko si ewu rara fun ọkọ oun.

Ariwo tun sọ lọdun 2022 pe Olu Jacobs papoda

Ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2022 ni iroyin kan tun lu ori ayelujara pa wi pe agbaọjẹ oṣere tiata, Olu Jacobs ti jade laye.

Bayii ni ọpọ ieeṣẹ iroyin lori itakun ayelujara bẹrẹ si ni gbe iroyin naa lai ṣe iwadii lati rii daju bo ya lootọ ni iroyin naa.

Lẹyin naa ni iyawo rẹ, Joke Silva, kede pe ko si ohun to jẹ bẹẹ.

Koda, Joke Silva tun sọ pe oun ṣetan lati gbe awọn to n gbe iroyin ofege nipa ọkọ oun kaakiri lọ ile ẹjọ.

Iroyin tun lu ori ayelujara pa lọgbọnjọ oṣu Kẹfa ọdun 2024 pe Olu Jacobs ti papoda

Ọjọ Aiku ọgbọnjọ oṣu Kẹfa ọdun 2024 ni iroyin kan jade pe Olu Jacobs ti jade laye.

Bayii ni ọpọlọpọ bẹrẹ si pin iroyin yii kaakiri ori itakun ayelujara lai ṣe iwadii nipa iroyin ti wọn n gbe kiri.

Ilumọọkan oniroyin, Betty Irabor, lo kọkọ sọ pe irọ nla ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kaakiri wi pe agba oṣere naa ti jade laye.

Irabor sọ loju opo X rẹ pe ko si ohun to ṣe Olu Jacobs, o si ni kawọn eeyan kọ eti ikun si ahesọ rọ tawọn eeyan kan n gbe kaakiri.

Lẹyin naa ni Soji Jacobs to jẹ ọmọkunrin akọkọ agba oṣere naa ṣafihan baba rẹ ninu fidio kan ninu eyi ti wọn ti ba a fa irungbọn funfun rẹ.

Joke Silva sọrọ lori aisan to n ṣe ọkọ rẹ Olu Jacobs

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju lọdun 2021 ni gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Joke Silva ti sọrọ lori ilera ọkọ rẹ, Olu Jacobs.

Ninu ifọrowerọ pẹlu awọn akọroyin, Joke Silva sọ pe o ti to ọdun diẹ sẹyin ti Olu Jacobs ti n ba aisan to maa n mu ki eeyan gbagbe nnkan, Dementia, finra.

Joke sọ pe "o ti n ba aisan Dementia finra lati nnkan bii diẹ meji sẹyin, aisan naa fara jọ aisan to maa n mu ki ara eeyan ma gbọn ( Parkinson), ọpọlọ lo si maa n doju kọ."

O fi kun pe "igba akọkọ ree ti n o sọrọ nipa aisan ọkọ mi ni gbangba, ṣugbọn mo ti mọ tẹlẹ pe ọjọ kan naa ni mo maa sọrọ nipa rẹ."

Joke Silva tun sọrọ nipa bi oun ati awọn mọlẹbi rẹ ṣe n farada aisan Olu Jacobs.

O ni "ko rọrun fun un nitori ko fi bẹẹ ni oye ohun to n ṣẹlẹ ati bo ṣe ri lara awọn mọlẹbi rẹ, ṣugbọn a fi ọpẹ fun Ọlọrun."

Agba oṣere naa fi kun pe lẹnu lọọlọ yii ni awọn ṣẹṣẹ la awọn ohun kan kọja, ti oun ko le maa sọ ni ojukaye.

Joke sọ pe "a ti la awọn nnkan kọja lẹnu ọjọ mẹta yii ṣugbọn a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun anfani to fun wa lati le maa koju awọn ipenija naa, emi ati ọkọ mi n saaro awọn igba ti a ti dọjọ ṣiṣẹ papọ sẹyin."

Àkọlé fídíò, Dementia: Máṣe pe arúgbó rẹ ní àjẹ́ tàbí wèrè torí pé làákàyè rẹ̀ ń ṣíṣẹ kíṣẹ́ lọ́jọ́ ogbó

Ẹbí Olu Jacobs sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ariwo gbalẹ̀ pé àgbà òṣèré náà jáde láyé

Aworan Olu Jacobs ati Joke Silva

Oríṣun àwòrán, Joke Silva/Instagram

Ebi agbaọjẹ oṣere tiata, Olu Jacobs ti kede wi pe ṣaka lara baba da lẹyin iroyin kan to kan kalẹ lana ọjọ Aiku pe o ti jade laye.

Ọmọkunrin akọkọ agba oṣere naa, Ọgbẹni Soji Jacobs lo sọ fun ileeṣẹ tẹlifisan Channels niluu Eko pe baba oun ṣi wa laaye.

Koda, Soji tun pin fidio baba rẹ kan pẹlu Channels ninu eyi ti agba oṣere naa ti jokoo ti wọn ṣi n ba a fa irungbọn rẹ funfun.

Ninu fidio ọhun ni Olu Jacobs ti n takurọsọ pẹlu ẹni to n gẹrun fun un atawọn eeyan to wa nibẹ pẹlu rẹ.

O kere tan, o ti ju igba meji lọ bayii tawọn eeyan kan ti tufọ agba oṣere naa lati inu oṣu Kọkanla ọdun 2021 ti aya rẹ, Joke Silva ti sọ faraye nipa aisan to n ba ọkọ rẹ finra.

Amọ, gbogbo igba ni ẹbi rẹ ti n kede pe iroyin ofege lawọn eeyan kan n gbe kiri, lọpọ igba ṣi ni wọn maa n ṣafihan fidio tabi fọto rẹ ki awọn eeyan le mọ pe lotitọ lo ṣi wa laaye.

"Arun 'Dementia' to nii se pẹlu ọjọ ogbo eyi to n mu ki ọpọlọ maa se isẹkisẹ lo n ṣe Olu Jacobs"

Ti ẹ o ba gbagbe, agba oṣere, Joke Silva, ti ṣalaye ṣaaju pe arun to nii se pẹlu ọjọ ogbo, eyi to n mu ki ọpọlọ maa se isẹkisẹ, taa mọ si Dementia to n ṣe ọkọ rẹ, Jacobs ni ko jẹ ki o le maa kopa ninu ere mọ.

Joke Silva ṣalaye nigba naa pe o ti to bii ọdun meloo kan ti arun naa ti n ṣe Ọgbẹni Jacobs.

‘’Arun yii ti ṣakoba fun ọkọ mi debi wi pe ko mọ ohun to n lọ layika rẹ mọ.

Oniruuru iṣoro ni a ti la kọja gẹgẹ bi ẹbi, koda, o maa n ṣe mi bii ki ara ọkọ mi ṣa ṣaka ko maa ba jẹ pe emi nikan ni mo n la gbogbo ipenija kọja.

Mo ṣi n ṣafẹri awọn akoko ti a jọ ṣiṣẹ papọ, amọ ju gbogbo rẹ lọ, a dupẹ lọwọ Ọlọrun,’’ Arabinrin Silva ṣalaye.

Ọpọ igba awọn eeyan ti ri agba oṣere yii nibi ayẹyẹ pẹlu aya rẹ lẹgbẹẹ rẹ to duro ti i.