Ghali Na’Abba,Olórí ilé aṣojúṣòfin tẹ́lẹ̀ tó gbéná wojú Ààrẹ Obasanjo jáde láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe Ghali Umar Na'abba to jẹ olori ile aṣojuṣofin Naijiriia nigba kan ri ti dagbere faye.
O ku si ile iwosan kan nilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria nibi to ti n gba itọju.
Mọlẹbi rẹ fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC lowurọ Ọjọru.
Ẹni ọdun marundinlaadọrin ni Ghali Na'abba jẹ.
Ọmọ bibi ilu Kano ni Na'abba.
Iroyin taa ri gbọ lẹnu awọn ẹbi rẹ sọ pe wọn ti n ṣe ipalẹmọ lati gbe oku rẹ lọ sin nilu Kano.
Nigba aaye rẹ, Na'abba lo dari ile aṣojuṣofin Naijiria laarin ọdun 1999-2003.
Ọpọ lo mọ lagbo oṣelu Naijiria pẹlu awọn iyipada ati ilana to gbe kalẹ ni ile aṣojuṣofin akọkọ lẹyin ti Naijiria pada si ijọba awarawa.
Ni paapa awọn eeyan ko ni gbagbe bo ṣe lewaju idojukọ aarẹ tẹlẹ Olusegun Obasanjo ti awọn ile aṣojuṣofin sọ pe ko bọwọ fun ofin pẹlu awọn igbesẹ to n gbe nijọba.
Fakinfa laarin awọn mejeeji yi lo han si gbogbo ọmọ Naijiria pẹlu bi awọn mejeeji ti ṣe n wa ọna lati fa iṣubu ara wọn.
Na'aaba ati awọn ọmọ ile gbiyanju lati yẹ aga nidi aarẹ bẹẹ naa si ni aarẹ naa pete titi ti Na'abba fi fi ipo silẹ lọdun 2003.
O gbiyanju lati pada si ile ninu idibo ọdun 2003 amọ ipetepero ko jẹ ki o ribi pada sile mọ labẹ asia ẹgbẹ Peoples Democratic Party.
O pada sile ṣugbọn awọn eeyan a maa kan si gẹgẹ bi agbaọjẹ oloṣelu

Oríṣun àwòrán, Getty Images












