Ta ni Betty Akeredolu ń ta Kókó ọ̀rọ̀ mọ́ létí aṣọ pẹlù ògiri ''Wall of Jericho'' tó ní kò yẹ kí wọ́n fọwọ́ kàn nílùú Akure?

Áworan iyawo Gomina Ondo Betty Akeredolu

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu

Awuyewuye kan ti bẹrẹ si ni rugbo bọ nipinlẹ Ondo pẹlu ọrọ ti iyawo Gomina Rotimi Akeredolu, Betty fi soju opo rẹ ni Facebook.

Ọrọ yi tawọn eeyan ti n sọ iriwisi wọn nipa rẹ lọ bayii pe ''saaju ki n to jẹ iyawo Gomina ni mo ti jẹ ajafẹtọmọniyan.A gbọdọ sọ ododo.''

Ko tan sibẹ, Arabinrin Betty fikun pe ''Ẹni ti ọrọ yi ko dunmọ,ko lọ di mọ ẹrọ amunawa 'transformer'''

Ni owurọ ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ keji ọdun Keresimesi lo gba oju opo rẹ ti oko ọrọ yi si bẹrẹ si ni rọ.

Akeredolu wa lẹnu aarẹ ti o si ti gbe agbara le igbakeji rẹ lọwọ lati maa ṣe akoso ipinlẹ Ondo titi ti ara rẹ yoo fi ya.

A ko le sọ boya ibi ti Gomina wa naa ni iyawo rẹ ti n fi ọrọ yi sita amọ oju opo rẹ to jẹ ojulowo ni Facebook la ti ri ọrọ yi.

Lọpọ igba si ni iyawo Gomina a maa kọ ọrọ si oju opo naa fun ara rẹ ti kii ṣe pe awọn amugbalẹgbẹ lo n kọ ọrọ sibẹ.

Ta wa ni iyawo Gomina n fi oko ọrọ ranṣẹ tọrọ fi di pe ki wọn lọ di mọ ẹrọ amunawa ti ko ba tẹ wọn lọrun?

Aworan iyawo Gomina Akeredolu ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu

Odi Jericho ilu Akure ti wọn yọ lo kọkọ mu ọrọ wa lati ẹnu iyawo Gomina

Aworan ọrọ tiiyawo Gomina Akeredolu kọ

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu

Awọn olugbe ilu Akure lọrọ odi Jericho ti iyawo Gomina Betty Akleredolu kọkọ fi bẹrẹ ọrọ lowurọ ọjọ Iṣẹgun yoo ye daada.

Odi taa n wi yi kii ṣe bi pe wọn mọ ogiri nla sibẹ amọ orukọ ti araalu fun awọn kọnkere ti wọn fi da ọna si meji ni wn n pe ni odi Jericho.

Odi wọnyi wa laarin ọna lopopona Adesida.

O ti to ọdun meloo kan ti ijọba gbe sibẹ lati fi da oju popo si meji.

Ijọba ọkọ rẹ Rotimi Akeredolu lo gbe awọn odi naa si aarin na.

O ti sunmọ ọdun meji ti odi yi ti la aarin titi ti ijọba si ni awọn tori aabo araalu gbe wọn sibẹ lati le dena ijamba oju popo lagbegbe naa.

Amọ pupọ araalu lo ni inira lodi naa mu ba awọn.

Koda awọn araalu kan sọ pe o maa n ṣe idiwọ lati ra nkan lọja Oba.

Lọjọ Aiku ti wọn fi katakata yọ odi yi pẹlu aṣẹ igbakeji Gomina to n ṣe adele Gomina lọwọ, niṣe laraalu n yayọ pe odi naa kuro nibẹ.

Aworan ọrọ iyawo Gomina Akeredolu lojoopo Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu

Alaye ranpẹ taa ṣe yi ṣe pataki ki ẹ baa le mọ idi ti iyawo Gomina fi n sọko ọrọ si awọn to ni ''oju aye ni wọn n wa'' pẹlu igbesẹ yiyọ odi Jericho yi.

Ninu ọrọ rẹ, Betty Akeredolu ṣalaye pe tori aabo araalu ni wọn fi ṣe odi yi sibẹ to si ni ki awọn eeyan ronu jinlẹ lori ọrọ yi.

A ko le sọ awọn eeyan to n gbero pẹlu ọrọ yi amọ niṣe ni awọn araalu fi idunnu wọn han nigba ti wọn yọ odi yi kuro ti wọn si n gba ibẹ kọja.

Ijọba ọkọ Betty naa la le sọ pe o gbe odi yi kuro nitori ẹni to n ṣe adele Gomina, iyẹn Lucky Aiyedatiwa naa wa ninu ijọba Gomina Akeredolu nigba ti wọn fi ṣe agbekalẹ awọn odi yi.

Bi a ba foju wo ọrọ naa o fẹrẹ jọ pe iyawo Gomina ko dun si bi wn ṣe mu ayipada ba igbesẹ ti ọkọ rẹ gbe ki aarẹ to de mọlẹ.

Awọn agbẹnusọ adele Gomina ko ti fesi si ọrọ yi amọ loju opo Facebook ti iyawo Akeredolu fi ọrọ yi si, awọn eeyan ti n sọ iriwisi wọn loriṣiriṣi

Itọju ọkọ rẹ lo yẹ ko gbajumọ kii ṣe ọrọ odi Jericho

Awọn araalu to bọ si oju opo iyawo Gomina Akeredolu lo n fọ esi bayii pe awọn ko lero pe ọrọ Jericho lo yẹ ki arabinrin Betty wa mọya lasiko ti ọkọ rẹ wa lori aarẹ.

Ninu awọn ọrọ yi taa ri, diẹ lawọn to sọ pe awọn gbe lẹyin iyawo Gomina.

Ọpọ lo sọ pe awọn ko nifẹ si odi yi ati pe ko tọ si iyawo Gomina lati maa da si ọrọ ti ko nii ṣe pẹlu ipadasipo alaafia Gomina Akeredolu.

Die ree lara awọn esi taa ri loju opo arabinrin Betty Akeredolu ni Facebook to fi ọrọ nipa odi Jericho si.

Aworan esi tawọn araalu fọ si ọrọ Betty Akeredolu ni Facebook

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu

Aworan esi ọrọ loju opo iyawo Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, betty.anyanwuakeredolu