Ohun tí a mọ̀ nípa ikú baba Bobrisky, gbajúmọ̀ ọkùnrin tó ń múra bí obìnrin

Aworan Bobrisky ati Baba rẹ

Oríṣun àwòrán, other

Baba to bi gbajugba okunrin to maa n mura bi obirin, Idris Odunẹyẹ ti gbogbo aye mọ si Bobrisky, ti jade laye

Bobrisky kede iku Baba rẹ lori opo ayelujara Instagram ni Ọkọ Kẹrinla, oṣu kẹjọ

"Ẹyin eeyan mi, Mo padanu Baba mi lowurọ oni."

Sugbọn ọkan lara ọmọ oloogbe, Debola Okunneye lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin.

O ni, "Bẹẹni, Baba mi ku lowurọ oni, a si ti bẹrẹ igbaradi eto isinku,"

Bakan naa ni Alagba kan ti ọpọ mọ si 'LastBorn', ẹni to jẹ ọrẹ oloogbe naa fidi isẹlẹ naa mulẹ pẹlu.

Wọn ti sin oku oloogbe naa ni ibamu pẹlu ilana ẹsin musulumi to ṣe nigba to wa laye.

Aworan Oju opo Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram

Baba wa jẹ eeyan to ko ẹbi mọra- Akọbi Oduneye

Akọbi Baba Musibau Oduneye ni gbogbo awọn mọlẹbi lo se idaro Baba nitori o jẹ ẹnikan to kọ ẹbi mọra pupọ.

"Baba ko fẹ ija larin mọlẹbi, to si ma se gbogbo akitan yan lati ri pe alaafia jọ ba laarin wa.

"Ti Baba ba gbọ nipa awọ laarin mọlẹbi ni Eko ni tabi Ijẹbu, wọn yoo gbera lọ sibẹ, wọn yoo pe ẹni kini ati ẹni keji, ti wọn yoo si yanju rẹ.

Akọbi Oduneye tẹsiwaju pe oun kọ ẹkọ pupọ lọdọ Baba oun ti oun naa si setan lati ko mọlẹbi mọra.

Oduneye Samiat, ro jẹ iyawo si ọkan lara ọmọ oloogbe ni Baba mu oun gẹgẹ bi ọmọ bibi inu rẹ, ti oun si nifẹ si pupọ.

"Lati igba ti mo ti wọ inu ile yii, ni Baba ko ti mu mi gẹgẹ iyawo ọmọ sugbọn gẹgẹ bi ọmọ.

"Eeyan gidi ni Baba wa, n ko ni Baba, o su mu mi gẹgẹ bi ọmọ.

"Ko si ẹni to ba ẹku wọ ile Alhaji Baba, ti ko ri ẹrin jade."

Taa ni Bobrisky?

Idris Odunẹyẹ ni orukọ abisọ rẹ sugbọn ti gbogbo aye mọ si Bobrisky

Ọdun 1991 ni wọn bi Bobrisky , to si bẹrẹ ile ẹkọ akọbẹrẹ ni ile ẹkọ King's High School ati Okota High School niluu Eko

O tẹsiwaju lọ Fasiti ilu Eko ni bi to kawe gboye imọ Accounting.

Ọkunrin to n se bi Obinrin ni ọpọ mọ Bosrisky mọ, to si ni ọpọlọpọ alatilẹyin lori ayelujara.

Bobrisky ni bi oun ṣe jẹ obinrin lọwọlọwọ yii, oun n gbadun rẹ gidi gan to si ti lana pupọ fun un.

Nigba to bii pe "Ọkunrin ni wọn bi ẹ, ki lo de too fẹ parada di obinrin", Bobrisky ni:

"Tori jijẹ obinrin bayii ti ṣi ọpọlọpọ ọna fun mi. Awọn obinrin o tilẹ mọ bi wọn ṣe lagbara to, ọpọ wọn ko mọ bi wọ́n ṣe le lo ẹbun ti wọn ni gẹgẹ bii obinrin".