'Gbogbo ọ̀nà tí àwọn ẹbí mi tó wà ní Niger yóò fi padà sí Nàìjíríà ni mo ń sá báyìí'

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ní àwọn ènìyàn ní orílẹ̀ èdè Niger kò ní ojú oorun mọ́ láti ìgbà tí àwọn ológun ti fipá gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà ló ní ìbáṣepọ̀ kan tàbí òmíràn pẹ̀lú àwọn ènìyàn Niger láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn.
Láti ìgbà tí ìdìtẹ̀gbàjọba tí wáyé ní orílẹ̀ èdè náà ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Keje ọdún 2023 léyìí tó yọ ààrẹ Bazoum kúrò nípò ni ìbẹ̀rù bojo ti ń wà pé ó ṣeéṣe kí oogun bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà.
Hudu Sulaiman (èyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gan) tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Kano, ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí pé àwọn ẹbí rẹ̀ wà ní Zinder, orílẹ̀ èdè Niger.
“Ṣaájú ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Keje, nígbà tí Bazoum ṣì jẹ́ ààrẹ Niger ni mo ti sun oorun gidi kẹ́yìn, ọkàn mi kò balẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí àwọn ológun ti gb ìjọba Niger.
“Gbogbo ìdúnkokò pé wọ́n máa kógun ja Niger ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bámi nítorí ìlàjì ẹbí mi ló wà ní Zinder ní orílẹ̀ èdè Niger.
“Gbogbo ìrònú tó gba ọkàn mi láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni láti wá bí àwọn ẹbí mi ṣe máa padà sílé, tí rògbòdìyàn kankan kò ní ṣojú wọn ní ilẹ̀ òkèrè tí wọ́n wà.”
“Ó tó ọjọ́ mẹ́rin tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wọn kẹ́yìn nítorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn kò já geere, ó kàn ń dákú dájí ni.”
Hudu ṣàlàyé pé ọmọ orílẹ̀ èdè Niger ni ìyá òun, ó ní ọdún 1970 ni bàbá òun gbé ìyá òun ní ìyàwọ ní Niger èyí tó túmọ̀ sí pé apá kan Nàìjíríà, apá kan Niger ni òun.
“Ó máa ń tó ìgbà mẹ́rin sí márùn-ún tí mo máa ń lọ Niger ní ọdún kan, mo ni oko tí mò ń dá níbẹ̀.”
Ó ní ẹni tí òun ń káàánú rẹ̀ jùlọ ni ẹbí ìyá òun tó ní ọmọ mẹ́fà, tí òun máa ń fi owó ránṣẹ́ sí láti Nàìjíríà àmọ́ tí ìdìtẹ̀gbàjọba tó ṣẹlẹ̀ yìí ti ṣe ìdíwọ́ fún.
Bí ẹyẹ bá ṣe lọ la ṣe ń sọ òkò rẹ̀
Hudu ní òun ti ń bá àwọn onífàyàwọ́ sọ̀rọ̀ láti bá òun kó àwọn ẹbí òun tó wà ní Niger wá sí Nàìjíríà, owó tí òun fi máa kó wọn wá lókù tí òun ń wá.
Ó ní tí kò bá sí ohun tó ṣẹlẹ̀, ènìyàn kan kò lè ná tó N80,000 láti fi wọ ọkọ̀ wá sí Nàìjíríà láti Niger àmọ́ iye tí àwọn onífàyàwọ́ ń bèèrè fún nìyẹn.

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹnubodè tí àwọn ènìyàn lè gbà wọ inú rẹ̀ láì sí àbójútó tó péye fún àwọn ẹnubodè náà.
Ó ní òun kò fẹ́ gba ọ̀nà tó tọ́ nítorí ìyẹn máa gba àkókò tí òun sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn òun máa bọ̀ ní Nàìjíríà kíákíá.
Ó fi kun pé ohun tó le mú òun yí ìpinnu òun padà ni tí ECOWAS bá ní àwọn kò ní kó ogun ja Niger.
A ti ṣetán láti bá ECOWAS jíròrò
Ẹ̀wẹ̀, ní ọjọ́ Àìkú ni àwọn ológun tó gbàjọba ní Niger ni àwọn ti ṣetán láti bá ECOWAS jíròrò lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú tó ń fa awuyewuye ní orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn olórí ẹ̀sìn láti Nàìjíríà lọ jẹ́ àwọn tí wọ́n máa bá àwọn ológun náà jíròrò tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìpàdẹ lọ́jọ́ Àìkú ní Niamey.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Sheik Bala Lau fi síta ní òun àti àwọn ìyókù òun ṣèpàdé pẹ̀lú ọ̀gágun Abdourahmane Tchiani fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, tí àwọn sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí ECOWAS ń fẹ́ kí àwọn olọgun náà ṣe.
Sheikh Lau ní òun ti sọ fún ààrẹ Bola Tinubu tó jẹ́ alága ECOWAS pé ohun tí ìjíròrò máa yanjú ni ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ àti pé òun sọ fún Ọ̀gágun Tchiani pé àbẹ̀wò àwọn ni láti báa àwọn olọgun náà sọ̀rọ̀ láti gba àláfíà láàyè dípò lílo ogun.
Ó ṣàlàyé pé Tchiani gba àwọn ní àlejò tó sì ní òun ti ṣetán láti jíròrò pẹ̀lú wọn àti pé ìdí tí òun kò fi bá àwọn tí ECOWAS kọ́kọ́ rán wá sọ̀rọ̀ kò ṣẹ̀yìn inú tó ń bí òun nítorí gbèdéke tí ECOWAS fún àwọn láti dá ìjọba padà fún Bazoum.












