Èèyàn 30 ló ti kú sínú ìjàmbá iná tó mú ilé èpò kan

Aworan Ibugbamu ile epo

Ko din ni ọgbọn eeyan to ti jade laye lẹyin ti ina sọ ni ile epo kan ni Dagestan lagbegbe guusu orilẹede Russia.

Ibugbamu naa waye ni Makhachkala ni nnkan bii ago mẹsan an kọja ogoji isẹju lọjọ Aje.

Ogunlọgọ eeyan lo farapa nibi isẹlẹ naa, ti ko si ti si akọsilẹ lori iye awọn to fara kaasa isẹlẹ naani pato .

Awọn aworan to jade lati ibi iṣẹlẹ ijamba ina ọhun ṣe afihan bi eefin ina se gba gbogbo oju ofurufu kan, to si ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.

Awọn Osisẹ adoola ẹmi ati iṣẹlẹ pajawiri ti wọn to ọtalelugba o din mẹwaa 250 lo ti bẹrẹ iṣẹ nibi ijamba ina naa ti wọn si .

bakan naani wọn si tun n lo awọn baluu kekeke lati ko awọn eeyan kuro nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Ileeṣẹ iroyin orilẹede naa sọ pe awọn Dokita ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn ọmọde mẹta wa lara awọn to padanu ẹmi wọn.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ba ileeṣẹ iroyin Izvestia sọrọ, wọn ṣalaye pe ibudokọ ayọkẹlẹ to wa niwaju ile epo naa ni ijamba ina ọhun ti kọkọ sọ.

"Bi ibugbamu naa se waye, gbogbo nnkan to wa lọwọ wa jabọ. A ko si ri nkankan mọ." Osojumikoro salaye.

Igbimọ Iwadi orilẹede Russia ni ibugbamu yii ko sẹyin bi ina se jade lara ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn n tun se lasiko naa.

Dagestan jẹ ọkan lara agbegbe mẹtadinlaalọgọrun lorilẹede Russia, to si wa ni guusu orilẹede naa.