Nǹkan dé! Franklin fi agbárí èèyàn wẹ̀ nílùú Akure

Aworan Awọn Afurasi

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti safihan ọkunrin kan, Franklin Akinyosuyi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti ọwọ tẹ pẹlu ori eeyan ni ile rẹ niluu Ondo.

Iṣẹ ayaworan ati onisowo ni Franklin n ṣe.

Amọṣa o ni babalawo kan lo dari oun lati maa fi ori eeyan wẹ lẹkan losu ni dede ago kan oorun ni gbogbo Ọjọbọ lati mu ọrọ aje burẹkẹ sii.

Akinyosuyi, ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi oju oun atawọn akẹgbẹ rẹ han lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa nilu Akurẹ.

Afuruasi ni ọwọ tẹ lẹyin ti Agbanisile rẹ fi ẹjọ rẹ sun ileeṣẹ ọlọpaa pe o gbe ori eeyan silẹ ni agbegbe Eleworo.

"Ayoworan ni mi, mo si n ta asọ. Ọdun to kọja ni ẹgbọn Baba mi mu mọ lọ Ile Babalawo. Mo salaye fun pe okowo mi kọ gboro, o wa sọ fun mi pe ki mu ẹgbẹrun lọna igba naira wa lati fi se awọn asejẹ, ti mo si san laarin ọsẹ mẹta.

"Lẹyin to setan, o pe mi lati wa gbe eni nnkan bii oṣu kọkanla ọdun to kọja. O ni ki ma fi ori eeyan yii wẹ ni gbogbo Ọjọbọ ni dede ago kan ooru lẹkan losu sugbọn n ko ri iyatọ kankan ninu okowo mi. Mo wa kesi Babalawo naa pe ko da owo mi pada.

"Lọjọ ti mo pinnu lati lọ gbe ori sọnu, mo gbe si ẹyinkule ile ti mo n gbe. ti mo si jade lọ, awọn mọ ayalegbe mi ri, wọn fi to baba wọn leti, oun lo pe ọlọpaa."

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fummilayo Odunlami ni eeyan marun un lo lọwọ sinu ẹsun naa sugbọn ọwọ ti tẹ mẹta, ti Ọlọpaa si n wa awọn meji yooku.