Banky W, Ọbaníkòró fìdí rẹmi láti ṣojú Ẹtí-ọ̀sà l’Àbújá, ilé ẹjọ́ ni pé kí Thaddeus Attah, tí Labour Party máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ

obanikoro

Ìdájọ́ kóótù Kò-tẹ́-mi-lọ́rùn: Banky W, Ọbaníkòró fìdí rẹmi láti ṣojú Ẹtí-ọ̀sà l’Àbújá

Gbajumọ akọrin ati oloṣelu nni, Bankọle Wellington tawọn eeyan mọ si Banky W ati ẹnikeji rẹ, Babajide Ọbanikoro ni kootu Ko-tẹ-mi-lọrun ti fidirẹmi.

Ile ẹjọ fidi e mulẹ, pe wọn fidi rẹmi ninu atundi ibo to waye nijọba ibilẹ Eti-Ọsa. Ile-ẹjọ sọ pe Thaddeus Attah, ọmọ ẹgbẹ osẹlu Labour lo jawe olubori.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Banky W ti dije fun ipo asọju ẹkun ijọba Eti-Ọsa niluu Abuja,

Nigba ti Babajide Ọbanikoro naa dupo yii ninu ẹgbẹ ọselu APC, ninu ibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun yii.

Ṣugbọn Thaddeus to dije labẹ asia Labour ni wọn lo jawe olubori nigba naa.

bajade esi ibo naa ni Banky W ati Ọbanikoro tako, ijokoo awọn asọfin agba to n ri si awuyewuye ninu ibo si kede loṣu kẹsan-an, pe awọn fagile esi ibo to gbe Attah wọle.

Wọn ni idibo ko waye lawọn ibudo idibo kan leti -Ọsa, wọn si pe fun atundi ibo lati ọwọ ajọ INEC, eyi ti wọn ni ko waye nibudo idibi mẹtalelọgbọn laarin aadọrun-un ọjọ (90 days).

Kini o selẹ nile ẹjọ?

Ṣugbọn ninu idajọ ile-ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun to waye lỌjọbọ ọsẹ yii, ni gbagede Tafawa Balewa niluu Eko, Adajọ sọ pe igbimọ to pe fun atundi ibo ko ṣe daadaa rara.

O ni idi ni pe awọn ẹri ti wọn ko kalẹ ko nipọn rara to ohun ti ofin ajọ eto idibo la kalẹ.

Adajọ sọ pe ọrọ ibo naa ko tilẹ kan awon mi-in ninu awọn to waa ṣe ẹlẹrii ni kootu.

Lori eyi ti wọn si sọ pe idibo ko waye lawọn ibi kan, Adajọ ni awọn olupẹjọ ni lati fi ẹri han pe ibo ti ko waye naa lo jẹ ki wọn fidi rẹmi.

Fun idi eyi, o paṣẹ pe Thaddeus Attah to dije ninu ẹgbẹ Labour to si ni ibo ẹgbẹrun mẹrinlelogun ati marundinlọgọrin ( 24,075) lo wọle sipo Aṣoju Eti-Ọsa niluu Abuja.

Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹrun mejidinlogun, ẹgbẹta ati mẹrindinlaadọrin ibo ( 18,666) ni INEC kede ẹ pe Banky W ni ninu idibo ọhun, nigba ti wọn ni Ọbanikoro ni ibo ẹgbẹrun mẹrindinlogun ati ọkan le niẹẹdẹgbẹrin (16,901)

Bo tilẹ jẹ pe Ọbanikoro ni tiẹ ti ki Attah ku oriire lori aṣeyọri rẹ yii, sibẹ, nigba to n sọ ero rẹ lori idajọ tuntun naa, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC yii bu ẹnu atẹ lu idajọ naa.

O ni iṣẹ oroju ni Adajọ ṣe pẹlu bi ko ṣe tu idi ẹjọ naa desalẹ ko too dajọ.

Ọbanikoro sọ fun ẹka iroyiun BBC to ba sọrọ, pe ọpọ iwe to yẹ ki Adajọ naa yẹwo ni ko wo, bẹẹ ọdọ INEC lawọn ti ko awọn ẹri naa wa.

O lo yẹ ki ajọ awọn NBA ri si idajọ yii, ki wọn le ri ohun toun n sọ.