Sultan Sokoto kéde rírí oṣù, ìbẹ̀rẹ̀ àwẹ̀ Ramadan ní Nàìjíría

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Aafin Sultan ti ilu Sokoto ti kede pe awọn ti ri oṣu tuntun to le lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria ni alẹ ọjọ Ẹti.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita , Sultan ilu Sokoto, Sa'ad Abubakar kẹta sọ pe riri oṣu kaakiri awọn agbegbe kan ni Naijiria ti fihan pe awẹ Ramadan yoo bẹrẹ ni ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kinni oṣu kẹta , ati ọjọ kinni oṣu Ramadan 1446.
Awọn alaṣẹ ulẹ Saudi pẹlu ti ṣaaju kede lile oṣu ni ọdọ wọn ti wọn si kede ọjọ Satide kan naa gẹgẹ bi ọjọ àkọkọ oṣu Ramadan lorilẹẹdẹ Saudi.











