Kà nípa bí ìwọ nàá ṣe lè rí oṣù ààwẹ̀ Ramadan

Oríṣun àwòrán, X/INSHARIFAIN
Lile tente oṣu Ramadan ni awọn Musulumi kaakiri agbaye fi maa n bẹrẹ aawẹ Ramadan, oṣu naa ni wọn yoo si ri ti wọn yoo fi kadi aawẹ naa nilẹ lẹyin oṣu kan.
Fun Ramadan ọdun 2025 yii, oni ọjọ Jimọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2025 ni awọn Musulumi yoo ti maa wa oṣu tuntun, ki wọn le bẹrẹ aawẹ Ramadan ọdun yii.
Sultan ilu Sokoto, Sa'ad Abubakar, ti rọ awọn Musulumi lati bẹrẹ si i wo oju ọrun fun oṣu naa, nitori ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji ti a wa yii ni i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Sha'aban, 1446 AH.
Eyi si jẹ oṣu oju ọrun ti awọn Musulumi n lo fi ṣe onka ọjọ ati ọdun wọn.
Bi ẹnikẹni ba ri oṣu naa, atẹjade lati aafin Sultan sọ pe ki wọn fi to wọn leti ni aafin yii, nipasẹ awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn ti fi sita.
Bakan naa lọrọ ri ni Saudi Arabia, Ọjọruu ni ile-ẹjọ to ga julọ nibẹ ti fi atẹjade sita, pe kawọn Musulumi fi oju sita lọjọ Ẹti lati wa oṣu aawẹ Ramadan ti ọdun yii.
Báwo ni wọ́n ṣe ń rí oṣù?

Gẹgẹ bi Simwal Usman Jibrin, onimọ nipa wiwa oṣu oju ọrun, to si tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ to n wa oṣu nipinlẹ Sokoto ṣe ṣalaye, o ni nigba ti oorun ba ti wọn ni eeyan maa n wa oṣu.
"Nigba ti oorun ba ti wọ la maa n wa oṣu, nitori lọjọ kọkandinlọgbọn,oṣupa ati oorun maa n yọ si asiko kan naa ni, wọn yoo si tun jọ wọ̀ si asiko kan naa.
"Lati ri oṣu, eeyan ni lati duro fun bii iṣẹju mẹwaa lẹyin ti oorun ti wọ, nigba ti oju ọrun ba ti n dudu, nitori asiko kan ṣoṣo ti eeyan le ri i oṣupa naa niyẹn, nigba ti oorun ko ba fi gbogbo ara bo oṣupa mọ."
Bí o ṣe lè rí oṣú Ramadan ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, X/INSHARIFAIN
Simwal, onimọ nipa oṣu wiwa naa ṣalaye pe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Sha'aban (oni) ni afojusun wa pe oṣu tuntun Ramadan yoo yọ nigba ti oorun ba ti wọ.
"Pẹlu ogo Ọlọrun, oṣu ọdun yii yoo yọ lasiko kan naa ti oorun n wọ"
Simwal lo sọ bẹẹ.
Bẹẹ lo tun ṣalaye awọn igbesẹ ti eeyan ni lati tẹle to ba fẹẹ ri oṣu Ramadan tuntun.
Akọkọ ninu awọn nnkan naa bo ṣe ka a ni:
*Wa nibi ti aaye wa.
*Maa reti igba ti oorun yoo wọ.
*Lẹyin iṣẹju mẹwaa,wo apa ibi ti oorun ti n wọ.
Kí ló lè má jẹ ká rí oṣù Ramadan lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣu Sha'aban?
Ọpọlọpọ idi lo wa to le dena ki eeyan ma ri oṣu Ramadan nigba to yẹ ki wọn ri i, to si le fa ki wọn ma ri i lonii ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Sha'aban.
Bi Simwal ṣe ṣalaye fun BBC, o ka awọn nnkan wọnyi bi idena to le ma jẹ ki wọn ri oṣu tuntun:
*Nigba ti oorun ati oṣupa ba wọ nigba kan naa.
* Nigba ti ko ba to iṣẹju mẹwaa laaarin asiko ti oorun n wọ ati igba ti oṣupa n ran.
* Nigba ti oṣupa ba kọja laaarin aye ati oorun.
* Nigba ti oṣupa ba wọ ṣiwaju oorun
*Nigba ti kurukuru ba bo oju ọjọ.













