Ààlà wo ló wà láàrín títọ́ ọmọ àti ìfìyàjẹ ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ nipa ẹtọ ọmọde lorileede Naijiria ti sọ pe iyatọ wa laaarin fifi iya jẹ ọmọde lọna aitọ ati biba ọmọ wi, ati pe pupọ ni oye naa ko ye.
Laipẹ yii ni fọnran olukọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ aladani ti Christ Motits International jade sori ayelujara, nibi ti olukọ naa, Stella Nwadigo ti n fiya jẹ akẹkọọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹta.
Fọnran naa lo si ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ lorileede Naijiria, nibi ti awọn kan ti n sọ pe ọdaju abiyamọ ni Stella pẹlu bo ṣe lu ọmọ naa lai wo atubọtan iwa rẹ.
Nigba to n sọrọ, Amofin Toyin Taiwo-Ojo, to jẹ alakoso ajọ Stop The Abuse Against Women and Children Foundation, Lẹgal Practitioner sọ fun BBC YORUBA pe ifiyajẹ ọmọde lọna aitọ jẹ "fifi apa si ara ọmọ, ati jijẹ ki ọmọ naa ni ẹdun ọkan to ma maa ko ironu ba a ni gbogbo igba, to si yatọ si wi pe a n ba ọmọ wi."

Oríṣun àwòrán, Toyin Ndidi Taiwo-Ojo/Facebook
Amofin Taiwo-Ojo jẹ ko di mimọ pe biba ọmọ wi jẹ eyi ti awọn n ṣe lati tọ ọmọ sọna, ki wọn yipada kuro ninu iwa ti ko dara.
Bakan naa ni sọ pe fifi iya jẹ ọmọde lọna aitọ jẹ lati fiya jẹ ọmọ nipa dida apa tabi ọgbẹ si ọmọ lara.
"Lọpọ igba, lati ṣagbekalẹ ibawi, ko gbọdọ si apa lara ọmọ naa bo ti wu ko kere mọ, Ṣugbọn nigba ti a ba n sọ nipa fifi iya jẹ ọmọ, eyi ni pe a fẹẹ da apa si ọmọ naa lara ni," Taiwo-Ojo sọ bẹẹ fun BBC.
O tẹsiwaju pe "Ninu fọnran to n tan kaakiri yẹn, a maa rii pe ọmọ ọdun mẹta pere lọmọ naa, to ba jẹ pe ka kan ba ọmọ wi lasan ni, niṣe lo yẹ ka kan rọra gba ọmọ naa lẹyin-atẹlẹwọ, lati le jẹ ko ṣe atunṣe.
"Ṣugbọn nipa gbigba ori ọmọ naa pẹlu ipa, tabi fifi ori ọmọ naa gba ogiri tabi nnkan miran to le ṣe ipalara fun ọmọ naa, ifiya jẹ ọmọde ni.
"Mo maa ni lati jẹ ki ẹ mọ pe ilana biba ọmọde wi kaakiri agbaye ko faaye gba obi tabi ẹnikẹni lati lo ohun ija oloro lati fi ba ọmọde wi. Pẹlu eyi, awọn nnkan bii ẹgba, bẹliiti ati oniruuru ohun elo miran jẹ eyi ti ni erongba lati ṣe ipalara fun ọmọ naa.
"Nigba ti a ba lo awọn nnkan wọnyi, o ti tapa si ofin ifiyajẹ ọmọde lọna aitọ, bo tilẹ jẹ pe iyatọ wa. Nigba miran, a le lo ẹgba, ṣugbọn ẹgba ti ẹ fẹẹ lo yii, yoo jẹ eyi ti ko nii fi apa si ara ọmọ naa.
"Ohun ti a n gbiyanju lati ṣe ni pe ka tọ ọmọ naa sọna to ye kooro, kuro lawọn nnkan to n ṣe, eyi ti ko dara, ka si jẹ ko mọ, ṣugbọn nitori pe awọn eeyan ko mọ iyatọ nipa ifiya jẹ ọmọ ati biba ọmọ wi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Taiwo-Ojo sọ pe ọpọ igba ni awọn ti ṣe ipolongo lati sọ fawọn eeyan pe ki wọn dẹkun lati maa lo ẹgba tabi awọn nnkan ija oloro lati fi ba ọmọde wi, nitori pe ipalara to n ṣe fun wọn pọ ju rere rẹ.
"Gẹgẹ bi abiyamọ ti mo jẹ, emi naa ti gbiyanju rẹ wo lọpọ igba, mo si rii daju pe lilu ọmọde kọ la fi n tọ ọmọ sọna tabi ba ọmọ wi, bi ko ṣe pe ka gbe ilana kalẹ lori ohun ti awọn ọmọ wa gbọdọ ṣe," Amofin naa sọ bẹẹ.
Siwaju sii lo ni ọpọlọpọ orileede lo wa ti wọn ko gba awọn eeyan laaye lati lu ọmọ wọn, ti awọn ọmọ naa si n dagba ninu ilera pipe.
O ni iyalẹnu ati ibanu nla lo jẹ pe "lorileede ti a ti nigbagbọ ninu ka maa lu ọmọ nitori pe a fẹẹ ba wọn wi, naa la ti wa ni awọn gbajugbaja ọdaran bii Anini, Oyenusi ati awọn miran ti wọn pọ lọgba ẹwọn.
"To ba jẹ pe lilu ọmọ lo n jẹ ki wọn yipada ni, a ko nii ni iru awọn ọdaran nla wọnyi," o ṣalaye.
Taiwo-Ojo wa gba gbogbo obi, alagbatọ ati olukọ lamọran pe ki wọn dẹkun ilana biba ọmọ wi, eyi ti wọn gbọnju ba – ki wọn si boju wo ọna miran to le fi wọn lọkan balẹ lati tọ ọmọ sọna, dipo ki wọn maa fiya jẹ ọmọ, ti wọn si ro pe niṣe lawọn n ba a wi.

Oríṣun àwòrán, Favour Benson/Facebook
Alakoso agba ni Favour Benson jẹ nileeṣẹ ajọ Jashabel Touch-A-Heart Foundation, ẹni to jẹ ko di mimọ pe nigba ti obi tabi olukọ ba n ba ọmọ wi, wọn gbọdọ gbajumọ awọn daradara to wa nibẹ ju ipalara lọ.
"Nigba ti a ba sọ pe a n ba ọmọ wi, o ṣe pataki lati gbajumọ ipa rere, ibọwọ ati pataki to wa nibẹ," Benson sọ fun BBC.
Benson tọka si koko pataki mẹjọ ti awọn obi, alagbatọ olukọ ati paapaa awọn eeyan ni lati mọ, to ba di ọrọ wi pe wọn fẹẹ ba ọmọ wi.
Nini suuru ati ibalẹ ọkan
A ni lati ni suuru nigba ti ba sọ pe a n ba ọmọ wi. Bi a ba n pariwo tabi fi ibinu ba awọn ọmọde sọrọ lasiko ti a n ba wọn wi le jẹ ki nnkan tun buru sii.
Gbigbaju mọ iṣesi, kii ṣe ọmọ naa
Ẹ jẹ ka yago fun lilo awọn ọrọ abuku tabi ọrọ ti ko dara lati maa fi ba ọmọ wi, iyẹn awọn ọrọ bii 'o ti ya were', ni ko dara to. Dipo eleyi, ẹ jẹ ka ṣalaye ohun to ṣe ti ko dara. Gbigba ọmọde nigbakugba ko dara rara, o maa n ṣe ipalara fun awọn miran ni.
Lilo awọn ọrọ to dara
Ẹ ni lati maa lo awọn ọrọ to dara ni gbogbo igba, iyẹn nigba ti wọn ba n ṣe ohun to tọ. Fifun awọn ọmọde ni ẹbun to jọju nigba ti wọn ba ṣe ohun to dara tun maa n jẹ ki wọn tẹra mọ iwa rere ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jijẹ awokọṣe iwa rere
Awọn ọmọde maa n kọ ẹkọ nipa iwoye ni. Ẹ ni lati ṣagbẹkalẹ ilana to dara nipa awọn iwa ati awọn ọrọ ẹni yin ni gbogbo igba.
Fi fun wọn ni anfaani lati ṣatunṣe aṣiṣe wọn
Ẹ fun awọn ọmọde ni anfaani ati aye lati ṣatunṣe si iwa ti wọn hu, eyi ti ko dara. Eleyii yoo jẹ ki wọn le mọ pataki nnkan, ati bi wọn ṣe le yanju iṣoro to ba dide lọjọ iwaju.
Didena ọrọ abuku nita gbangba
Ẹ jẹ ka ba wọn wi ni kọọrọ iyara, ka si dena ṣiṣe ohun ti yoo ti wọn loju nita gbangba, ka le daabo bo wọn.
Wiwo ọjọ ori
Ẹ jẹ ka lo ọjọ ori wọn lati fi ṣe odiwọn iru ibawi ti wọn nilo, ka si lo ọgbọn ati imọ wọn pẹlu. Awọn ọmọde nilo ọrọ amọran ti yoo ye wọn yekeyeke, nigba ti awọn to ba ti n dagba nilo ijiroro to kunna.
Fifi ifẹ han ati igbarukuti to ye kooro
Ni gbogbo igba, a ni lati maa fi ifẹ han si awọn ọmọde, koda lẹyin ti a ba ṣẹṣẹ ba wọn wi tan, eyi yoo jẹ ki wọn mọ pe aabo to peye wa fun wọn, ati pe wọn ṣe pataki.
"Awọn ilana yii maa n ran biba ọmọde wi lọwọ, lọna to dara, nipa idagbasoke, ibọwọ ati oye ninu," Benson kadi ọrọ rẹ.















