Ilé-ẹjọ́ ju olùkọ́ tó lu akẹ́kọ̀ọ́ nílùkulù sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police/X
Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria ti wọ olukọ kan, Stella Nwadigo, ẹni to lu akẹkọọ, ọmọ ọdun mẹta kan, Abayọmi Michael lọ si ile ẹjọ lati lọ foju winna ofin.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo fidi rẹ mulẹ ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti 'X' rẹ l'Ọjọru, ọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025.
O ni ileẹjọ Majisireeti to wa ni agbegbe Ogba, ni igbẹjọ naa ti waye.
Nwadigo to n ṣiṣẹ olukọ nile-ẹkọ Christ Mitots to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko ni fọnran rẹ jade sori ayelujara laipẹ yii, nibi to ti n lu ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹta, to wa ni kilaasi rẹ.
Ọjọru, ọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 lọwọ tẹ ẹ olukọ naa, lẹyin to huwa ọdaran naa.
Fọnran naa lo di tọrọfankale, ti ọpọ eeyan si bu ẹnu atẹlu ihuwasi olukọ naa.
Ileẹjọ ti wa palasẹ pe, ki afurasi naa lọ ma gba atẹgun lọgba ẹwọn kirikiri, to si sun igbẹjọ naa si ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji ọdun 2025.
Ile-ẹkọ da Nwadigo duro

Oríṣun àwòrán, Toyin Ndidi Taiwo-Ojo/Facebook
Awọn alakoso ile-ẹkọ Christ Mitots naa ti sọ pe awọn ti da Stella Nwadigo duro gẹgẹ bi olukọ ati oṣiṣẹ ile-ẹkọ wọn, lori iwa aṣemaṣe to hu.
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ile-ẹkọ naa gbe jade, wọn jẹ ko di mimọ pe iwa adojutini gbaa ni obinrin naa hu, ti awọn ko si le tẹwọ gba a, nitori to tako ilana ati ohun ti wọn duro fun un, gẹgẹ bi ile-ẹkọ.
"A ti mọ nipa iṣẹlẹ buruku to kan olukọ wa ati akẹkọọ wa kan, eyi to ti n tan kaakiri ori ikanni ayelujara. Fonran naa ṣafihan iwa ti ko jẹ itẹwọgba gẹgẹ bi ilana ile-ẹkọ wa," awọn alakoso naa sọ bẹẹ.
"Ohun ti a duro fun ni lati ṣagbekalẹ idaabobo ati agbegbe titọ awọn ọmọ wa lọna to yẹ, ati pe iru iwa yii ni ko le faaye gba rara.
"Loju ẹsẹ lati gbe igbesẹ nipa dida olukọ tọrọ naa kan duro, nigba ti iwadii kikun n lọ lọwọ."
Awọn alakoso ile-ẹkọ naa wa rawọ ẹbẹ si awọn obi ọmọ naa lori ohun to ṣẹlẹ, pẹlu ileri lati duro ti titi idajọ ododo yoo fi waye.












