Mo ti pín gààrí pẹ̀lú Gani Adams àyàfi tó bá túbá lórí ẹ̀sùn tó fi kàn mí pé mo gba N35m lọ́wọ́ Tinubu - Alága OPC Ìbàdàn

Oríṣun àwòrán, other
Nnkan ko duro deede lẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC bayii labẹ Iba Gani Adams.
Eyi ko ṣẹyin bi Aarẹọna Kakanfo, Iba Gani Adams ati igbimọ to ga julọ lẹgbẹ naa ti ṣe fi ẹsun kan awọn alaga ẹgbẹ ọhun ni ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun pe wọn gba owo to to miliọnu marundinlogoji naira ati ọkọ ayọkẹlẹ landcruser.
Eyi ti mu ki ẹgbẹ naa yọ alaga rẹ ni ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Aladeṣawẹ ti wọn si fi Adeyẹmi Abọdẹrin rọpo rẹ.
Amọṣa alaga ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ Rotimi Olumọ ni oun atawọn ọmọlẹyin oun ni ipinlẹ naa ti pin gari nitori ohun to pe ni aini igbẹkẹle olori ẹgbẹ naa, Iba Gani Adams ninu oun pẹlu gbogbo ifọkansin oun ninu ẹgbẹ naa.
Rotimi Olumọ ṣalaye pe ẹsun ti wọn fi kan oun pe oun gba owo lọwọ oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo aarẹ to kọja, Bọla Tinubu jẹ eyi to ku diẹ kaato jọjọ nitori pe oun ko fi igba kankan ba oloṣelu kankan ṣe ri tabi kopa ninu eto oṣelu kankan bi o ti wulẹ o mọ.
Alaye ohun to fa edeaiyede naa
Nigba to tubọ n ṣalaye siwaju sii lori ohun to ṣẹlẹ, Rotimi Oluọ sọ pe igba meji ọtọọtọ ni wọn ni ki oun atawọn meji miran ti wọn fi ẹsun kan o bura sibẹ ti wọn ko gba oun gbọ.
O ni nigba ti oun atawọn ọmọlẹyin oun ni ipinlẹ Ọyọ wo ọrọ naa ni wọn fi fẹnuko pe bi o ba ṣe e ṣe ki Gani Adams ko ba ni igbẹkẹle ninu oun, yoo dara ki awọn kuro labẹ rẹ titi di igba ti o ba di pe igbẹkẹle naa yoo pada.
“Ero temi ni pe ibura ni a maa fi n ṣe oṣuwọn fun ọdalẹ... mo bura yẹn bi wọn ṣe fẹ, ẹnikeji mi naa bu.”
“Igbagbọ wa si ni pe bi a ti ṣe bura yẹn ki a wo bi ibura naa yoo ṣe ja.”
“Nigba to di ọsẹ keji ọga tun gbe ibura mii silẹ a tun bura lẹẹkeji.”
“Gbogbo rẹ ni mo si fi n to awọn ọmọ igbimọ mi ni ipinlẹ Ọyọ leti ti wọn si n sọ pe ko yẹ ko jẹ iru ọga ni yoo maa ṣe bẹẹ pẹlu gbogbo igbẹkẹle ti mo ni ninu wọn”
Nigba to di asiko idibo aarẹ, mo ri pe ọga (Gani Adams) ti n fi ara sọrọ. O di ẹni ti wọn n ran akọwe si mi.
'O digba ti Gani Adams ba tuba fun ibanilorukọjẹ yii ki a n to le ba a ṣe ohunkohun pọ'
O ni ohun to ba mu ki Gani Adams lee ṣiyemeji lori igbẹkẹle ati ijolotọ oun sii ati ẹgbẹ OPC.
Rotimi Olumo sọ siwaju si pe ọsẹ mẹrin ni Gani Adams ni ki wọn fun oun lati ṣe iwadi, awọn si tun fun un ni ọsẹ mẹrin miran lati fi jade sọ iwadi ṣugbọn titi di asiko yii ko si esi kankan to jade.
O ṣalaye pe bi Gani Adams ko ba jade lati sọ ibi ti o ti ri oun pẹlu owo tabi ọkọ ayafi ko bọ sita lati wa tọrọ aforiji fun ẹsun eke to fi kan oun, bibẹẹkọ ko ni si aṣepọ kankan laarin oun ati rẹ mọ.
Olumọ pari ọrọ rẹ pe igbesẹ naa waye pẹlu ajọṣepọ awọn ọmọlẹyin oun ni.
Amọ ṣa, gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati ba Iba Gani Adams sọrọ lori eyi lo ja si pabo pẹlu bi ẹni to n gbe aago ibanisọrọ rẹ ṣe n sọ pe oun ati agbẹnusọ rẹ ko si nitosi.












