Wo ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà nídìí lílo ẹ̀rọ kọ̀mpútà fún ìdánwò WAEC, tí ilé aṣòfin ṣe sún lílo rẹ̀ síwájú di 2030

Oríṣun àwòrán, WAEX/X
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria ti ni ki ajọ to n ri si idanwo oniwe-mẹwaa; WAEC, sun erongba rẹ lati jẹ ki awọn akẹkọọ maa lo ẹrọ kọmputa ṣe idanwo naa, bẹrẹ lati ọdun 2026 siwaju di 2030.
Ọjọbọ ana ti i ṣe ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn aṣofin panupọ, ti wọn si gba ọrọ naa wọle lẹyin ti aṣofin kan, Kelechi Wogu, da aba naa lasiko ipade wọn .
Aṣofin Wogu kilọ pe bi WAEC ba fi jẹ kawọn akẹkọọ bẹrẹ si i lo ilana kọmputa ti wọn n pe ni Computer Based-Testing, (CBT) ni 2026, ifidirẹmi alailẹgbẹ, idaamu ọkan ati wahala gidi ni yoo mu ba awọn akẹkọọ to ba ṣe idanwo naa.
Idi eyi bo ṣe wi ni pe ko ti i si igbaradi ati awọn nnkan eelo to le mu ki lilo kọmputa waye ni ọpọ ile ẹkọ.
O ni paapaa awọn to wa ni igberiko ti nnkan amayedẹrun bii ina ọba ko si .
Bẹẹ, ida aadọrin (70%) ni ai si nnkan amayedẹrun yii kan ninu awọn akẹkọọ ti yoo ṣe idanwo naa bi Aṣofin Wogu ṣe ṣalaye.
O fi ohun to ṣẹlẹ ninu idanwo WAEC to kọja ṣe akawe, nibi ti ọpọ akẹkọọ ti fidi rẹmi latari ẹrọ ti wọn lo da iṣẹ silẹ.
"Lati bẹrẹ ilana idanwo onikọmputa yii, gbọngan kọmputa to n ṣiṣẹ gbọdọ wa, itakun ti yoo jẹ ko ṣiṣẹ ti a mọ si internet gbọdọ wa ati ina ọba to duro lai ṣẹju.
" Ọpọlọpọ ile ẹkọ ni ko ti i ṣetan lati bọ si ilana iru eyi."
Bẹẹ ni Aṣofin Kelechi Wogu ṣalaye.
O ni o ya oun lẹnu pe ẹka ijọba to n ri si eto ẹkọ taku lati bẹrẹ si I lo CBT lati 2026, lai wo ti ajọ awọn olukọ ati awọn olori ile ẹkọ ti wọn ni awọn ko ti I lagbara lati maa lo ilana yii, paapaa awọn to wa ni igberiko.
Nibi ti ko si yara kọmputa, ti wọn ko ni yara ti wọn ti n gba ẹkọ lorii rẹ, ti ko si itakun intanẹẹti, ina ọba ati awọn tiṣa to nimọ nipa ẹkọ kọmputa.
Ko si bi ko ṣe ni I si ifidirẹmi to le kenka bi WAEC ba fi le gbiyanju iru rẹ bo ṣe sọ.
Ìgbèsẹ̀ àwọn aṣòfin láti yanjú ìṣòro yìí
Lati yanju iṣoro yii, ile igbimọ naa paṣẹ pe ki ileeṣẹ eto ẹkọ, pẹlu ajọṣepọ ijọba, fi awọn nnkan wọnyi kun iṣuna wọn fun 2026 titi de 2029.
Awọn nnkan naa ni:
*Gbigba awọn olukọ ti yoo maa kọ awọn akẹkọọ ni kọmputa.
*Kikọ awọn gbọngan kọmputa.
* Pipese itakun intanẹẹti ti yoo mu kọmputa ṣiṣẹ.
*Ati pipese awọn ọna miran ti ina mọnamọna yoo fi wa fun awọn ẹrọ naa lati ṣiṣẹ nigba ti ina ọba ko ba si.
Lẹyin eyi ni ile fẹnuko, pe ilana CBT yii ko ti i gbọdọ bẹrẹ ni 2026, wọn ni ki wọn da a duro di saa ẹkọ ọdun 2030.
Bakan naa ni wọn paṣẹ fun igbimọ to wa fun eto ẹkọ ati imọ ẹrọ, lati ba awọn ti ọrọ yii kan ṣe ipade, ki wọn si jẹ́ àbọ̀ ipade naa fun ile igbimọ leyin ọsẹ mẹrin.
Àjọ JAMB ló kọ́kọ́ lo CBT ní 2015
Ilana ẹrọ kọmputa lati ṣe idanwo yii kọkọ di mimọ ni Naijiria ni 2013, nigba ti ajọ Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB) gbe e de.
Wọn gbe ilana naa kalẹ lati kapa magomago to maa n waye ninu idanwo, ki wọn si tun le yi si ilana igbalode ti awọn ilẹ okeere n lo.
Ọdun 2015 gan-an ni wọn lo o lati ṣedanwo UTME akọkọ.
Latigba naa, ni awọn ajọ onidanwo mi-in bii National Examinations Council ati National Business and Technical Examinations Board, naa ti n fi ilana yii sinu idanwo won diẹdiẹ.
Ṣugbọn pẹlu rẹ naa, iṣoro ai si ẹrọ igbalode, ina ọba, itakun intanẹẹti ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣi n koju wọn.
Ṣaaju, oṣu Kẹsan-an ni ajọ WAEC kede pe oun yoo bẹrẹ CBT lọdun to n bọ, ti wọn si ni kọmputa bii aadọta din ni ọọdunrun (250), gbọngan rẹ, ẹrọ amunawa jẹnẹretọ ati bẹẹ bẹẹ lọ gbọdọ duro digbi ni awọn ileewe ti idanwo yoo ti waye.














