Ivory Coast, Guinea Bissau àti Equatorial Guinea ni ikọ̀ Super Eagles Nàìjíríà yóò kojú ní ìdíje AFCON 2023

Aworan Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Super Eagles/Instagram

Ikọ agbabọọlu Ivory Coast, Guinea Bissau àti Equatorial Guinea ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles yoo koju ninu idije ere bọọlu AFCON 2023 ti orilẹede Ivory Coast yoo gbalejo rẹ.

Ọpọ awọn gbajugbaja agbabọọlu to ti fẹyin ti bii Didier Drogba, Mikel Obi, Salomon Kalou to fi mọ olorin takasufee Akon lo wa nibi eto kikede awọn isọri ikọ agbabọọlu ti yoo kopa inu idije AFCON 2023.

Ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria, Victor Osimhen lo gba goolu sawọn julọ ninu idije ati pegede fun idije AFCON 2023.

Orilẹede Senegal ni ife ẹyẹ AFCON wa lọwọ wọn lẹyin ti wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON to wa kẹyin lorilẹede Cameroon.

Aworan Victor Osimhen

Oríṣun àwòrán, ng_supereagles/Instagram

Lonii ni ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria yoo mọ awọn ikọ agbabọọlu ti wọn yoo koju ninu idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2023 eleyii ti yoo waye lorilẹede Ivory Coast.

Gbogbo eto lo ti to bayii fun eto naa lati waye niluu Abidjan to jẹ ọkan lara awọn ilu nla lorilẹede Ivory Coast.

Isọri ikoko keji ti ọpọ mọ si Pot 2 ni Naijiria wa eleyii to tumọ si pe Super Eagles le koju ọkan ninu Senegal, Ivory Coast, Morocco, Algeria, Tunisia tabi Egypt.

Naijiria lo leke tente ninu idije ati pegede fun AFCON 2023 pẹlu ami mẹẹdogun ti wọn si gba goolu mejilelogun sawọn.

Mẹrindinlogun ninu awọn goolu yii ni wọn gba wọle ikọ agbabọọlu Sao Tome and Principe nikan.

Ipele keji ‘’round of 16’’ ni Naijiria ti ja kuro ninu idije AFCON to kẹyin eyi to waye lorilẹede Cameroon nibi ti Tunisia ti fagba han wọn pẹlu ami ayo kan sodo.

Igba mẹta ọtọtọ ni Naijiria ti gba ife ẹyẹ AFCON eyun n ni lọdun 1980, 1994 ati ọdun 2013.

Lọwọ yii, ikọ Super Eagles n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹ pẹlu Saudi Arabia ati Mozambique ti yoo waye lorilẹede Portugal.

Saudi Arabia ni wọn yoo kọkọ koju lọla ọjọ Ẹti ki wọn to koju Mozambique lọjọ Aje to n bọ.