Àlàyé ohun tó fa ìjàmbá iná tó sọ láàfin Ooni Ilé Ifẹ̀ rèé

Aworan ooni ati ibugbe to jona laafin

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Ọkan lara awọn ibugbe to wa ni aafin Ọọni ti ile Ifẹ, ni ilu ile ifẹ ti jona loru ọjọ Ẹti mọju Ọjọ Abamẹta.

Atẹjade kan lati ile Oodua tii ṣe Aafin Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Atẹjade ọhun ti aafin Oodua fi sita tun ṣe e lalaye pe ibugbe yii nikan ni ina naa mọ nitori ijafafa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ọgba fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile ifẹ, ileeṣẹ panapan ti ijọba ipinlẹ Ọṣun ati ẹka amojuto iṣẹlẹ pajawiri laafin naa.

ibugbe aafin to jona naa

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Agbẹnusọ fun Ọọni ile Ifẹ, Ọtunba Moses Ọlafare, pẹlu ṣalaye pe nnkan bii agogo mọkanla abọ alẹ ọjọ Ẹti ni ina naa bẹrẹ.

O fi kun un pe ina manamana to ṣe mọnamọna lo ṣokunfa bi awọn ohun elo ina ọba kan to wa ni ile igbe naa ṣe gbina ti ina naa si ran ka gbogbo ibugbe naa.

Agbẹnusọ fun ọọni ni ko si ẹnikẹni to ku tabi farapa ninu ijamba ina naa, bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo nnkan ọṣọ iṣẹmbaye gbogbo to wa nibẹ lo ṣi pe perepere.