Orí kó aṣejúlóge Hakeem Effect yọ lọ́wọ́ ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Instagram/Hakem Effect
Gbajugbaja aṣe-ojuloge sinima, Hakeem Ajibola ti ọpọ mọ si Hakeem Effect mu igbe ayọ bọ ẹnu lẹyin ti oei ko yọ lọwọ awọn ajinigbe.
Ninu fọnran to gbe sori ayelujara, o ni awọn ajinigbe yii ṣekọlu si oun ati awọn osisẹ lasiko ti wọn n rin irinajo kuro Ikenne nipinlẹ Ogun.
Hakeem Effect ni dẹrẹba oun lo dola ẹmi gbogbo awọn to wa ninu ọkọ akẹro ti wọn gbe lọ irinajo.
Ninu fọnran, o ni iro ibọn n lọ lọtun losi lasiko iukọlu naa, ti ibọn si ba dẹrẹba wọn to pe orukọ rẹ ni Legba.
O wa dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi oun ati akẹgbẹ rẹ si lasiko ikọlu awọn ajinigbe naa.
“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi o ṣe gba ẹmi emi ati awọn osisẹ mi la lẹyin ti awọn ajinigbe ṣekọlu wa ni bi ogun isẹju ti a kuro niluu Ikeene.
“Wọn fi ibọn fọ gilaasi ọkọ, ti wọn si ji awọn kan gbe sugbọn mo dupẹ pe mo mo wa laye.
“Mo dupẹ fun dẹrẹba ọkọ wa Legba ti wọn yin ibhọn lu, iro ibọn n dun lọtun losi sugbọn Ọlọrun ba wa wa ọkọ naa.
“Emi, Iyawo mi ati awọn osisẹ mi wa laaye.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















