Atiku pè fún ìdàpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò láti lè da APC lágbo nù

Oríṣun àwòrán, Global Eye TV
Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri ni Naijiria, Atiku Abubakar, ti rọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati parapọ ṣerawọn lọkan lati le gba agbara lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Atiku to jẹ oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo ọdun 2023 lo sọ ọrọ yii nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun lakoko to gbalejo awọn adari igbimọ to n moju to ibaṣepọ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu (IPAC) nile rẹ.
IPAC lawọn araalu ti ri bii ẹgbẹ oṣelu to ba wa lori aleefa kii ṣe ba awọn ẹgbẹ alatako ṣe pọ.
Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri naa to sọ pe APC ti fẹe sọ Naijiria di orilẹ-ede ẹlẹgbẹ oṣelu kan rọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati parapọ di ọkan lati lee gba ijọba lọwọ APC.
Atiku sọ fun Yabagi Sani to jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ naa lati wa ọna ti eyi yoo fi waye.
Bẹẹ lo kọ sori itakun ayelujara Twitter X pe “loni, ninu ipade kan pẹlu awọn alaṣẹ IPAC, mo sọ pataki idi taa fi gbọdọ daabo bo ijọba awa-arawa.''
''Mo sọ ẹdun ọkan mi lori igbesẹ ẹgbẹ oṣelu APC leyi to fẹẹ sọ Naijiria di ilu ẹlẹgbẹ oṣelu kan.''
O fikun pe oun rọ IPAC, labẹ idari Yabagi Sani, lati sẹ akojọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati di ọkan ki wọn lee koju ipenija yii.
O tẹsiwaju lati bẹnu atẹ lu ajọ INEC lori iṣeto idibo ti ko boju mu, to fi mọ iyapa laarin iye oludibo.
''Mo kesi ile aṣofin apapọ ilẹ yii lati gbajumọ tunṣe ofin ati ilana idibo ogbalode, paapaa julọ idibo pẹlu ẹrọ ayelujara lati lee jẹ ki eto idibo o ja gaara ka si lee daabo bo ijọba awa-arawa.''
Lakotan o ni oun nigbagbọ pe ijọba awa-arawa, lai fi ti kudiẹ-kudiẹ to wa nibẹ ṣe, ni eto ijọba to rẹwa ju.
O loun si ṣetan lati pawọpọ pẹlu awọn miran ni Naijiria lati daabo boo.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












