Queen Elizabeth II: Bí ìtàn ayé akọni obìnrin ṣe pin rèé

Obabinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi aago ṣe duro jẹ fun isẹju aaya, wakati kan, ọjọ kan, ọsẹ kan re e.

Eyi ni bi igbe aye Ọbabinrin Ilẹ Gẹẹsi ṣe lamilaaka kọja ọpọlọpọ ọdun. Bi o ṣe gbe igb aye rẹ lori aga, lasiko to n ba araalu sọrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

''Mi o ni okun lati da nikan gbe ẹru yii nikan fun ara mi''

Princess Elizabeth .

Oríṣun àwòrán, Topical Press Agency / Getty Images

Asiko ti awọn ara Ilẹ Gẹẹsi n koju iyan ogun agbaye igba naa. Arabinrin ti ko i tii ju ọdọ fun ara rẹ ni ọjọ iwaju rẹ bẹrẹ lairo tẹlẹ.

O ba awọn eniyan rẹ sọrọ ni agbaye, to si sọ fun awọn eniyan pe ohun to ni okun ati agbara lati danikan ṣiṣẹ ilu, to si kesi awọn eniyan lati ṣiṣẹ fun oun fun ọpọlọpọ ọdun.

Igba miran to tun sọrọ ni igba ti yipada. Aadọta ọdun ti kọja lẹyin rẹ, ti wọn si n ṣe ayajọ ọjọ ti ogun pari ni Ilẹ Gẹẹsi. Nise lo joko si ori ijoko rẹ pẹlu aworan baba rẹ, ọba to waja ninu Khaki ni ẹgbẹ rẹ. Erongba rẹ ni lati darapoọ mọ ikọ ọmọogun orilẹede naa bi baba rẹ.

Princess Elizabeth 12 April 1945.

Oríṣun àwòrán, Mirrorpix / Getty Images

Nipa ogun naa, ero re nip e gbogbo eniyan lo lọwọ ninu iṣẹḷẹ naa.

Nigba naa lohun lo n bẹ baba rẹ ki o jẹ ki ohun darapọ mọ awọn Ologun to n ja fun orilẹede oun, Amọ baba rẹ kọ jalẹ. Nibayii, lẹyin ọdun 75, pẹlu iwuri lo fi n ba awọn eniyan sọrọ lati ṣe ayẹyẹ iranti ipa akọni ti awọn Ologun ko ninu ogun naa.

Eyi safihan bi o ṣe fẹran iṣẹ ilu si ati bi o ṣe fi gbogbo ipa rẹ sin awujọ rẹ, to si ni bio tilẹ jẹpe oun ko mọ ọwọ ọtun yatọ si ti osi nigba ti o bẹrẹ, amọ o ni kosi ọrọ ibanujẹ Kankan ninu gbogbo ohun ti o sọ.

Queen Elizabeth II Balmoral. 6 October 1967

Oríṣun àwòrán, Central Press / Getty Images

''Wọn gbọdọ ri mi, lati gba mi gbọ''

Fun ọpọlọpọ odun to fi wa lori iṭ, kii sọrọ ni gbogbo igba, ti kii sit un aṣiri ara rẹ sita tabi jẹ ki awọn eniyan mọ ohun to n lọ. Bio tilẹ j̣pe asiko sọṛọ sọrọ ni wọn bii, ko figba kan fun awọn akọroyin ni anfaani lati ba sọrọ fun ifọrọwanilẹnuwo.

Ti o ba sọrọ ni gbangba a ajẹ ọrọ ti wọn jọ n jumọ sọ lọwọ lori ṣiṣ ara ẹni loge abi awọ ọrọ to fi n sere. O jẹ ẹni ti ko farasilẹ rara.

Amọ nigba ti iṣẹlẹ iku Diana waye, o ba awọn eniyan sọrọ ki wọn ba le mọ bi ọrọ naa ṣe ri ni ara wọn . amọ o jẹ eniyan kan to fẹran lati tele aṣa ati iṣe. Nitori naa bi oun gbogbo tilẹ n yipada, oun ko yipada

Queen Elizabeth II

Oríṣun àwòrán, PA Media

''Ohun kan to ba mi ninu jẹ nip awon eniyan ko ni aforiti de opin''

Ọbabinrin naa fẹran igberiko, ibẹ ni o si ma n lọ pẹlu awọn mọlẹbi rẹ , to fi mọ awọn ẹranko wọn.

O pẹlu awọn ti ko jẹ ki igberiko dagba nitori ati pa asa ati ise mọ.

Bi igba ati akoko rẹ ṣe nlọ, ti igba n yii ni Elizabsth di awokọṣe fun awọn abinrin ti wọn si bẹrẹ si ni ni ilọsiwaju lẹnu iṣẹ wọn, ti itẹsiwaju si n ba igbe aye awọn eniyan.

Bakan naa ni itẹsiwaju ba aafin ọba, ti awọn ọmọge lati ile olowo ko ni jẹ ohun elo ti wọn yoo ma fi paarọ ni aafin mṣ amọ ti wọn yoo maa wa si aafin lati se ayẹyẹ tabi idaraya lasiko to yẹ.

Queen Elizabeth II 11 December 1953.

Oríṣun àwòrán, Hulton Archive / Getty images

Awọn mọlẹbi rẹ faragba lasiko ijọba rẹ, ti ko si ri aye fun awọn ọmọ naa, gbogbo asiko to ni lo n lo fun ijọba, to si jẹ ọkọ rẹ Duke ni o ma n gbe igbesẹ to ba niise pẹlu awọn ọmọ wọn.

Eyi pẹlu ohun to jẹ ki igbeyawo mẹta ninu mẹrin awọn ọmọ rẹ fi ori sanpọn, to si ti sọ rip e oun ko faramọ nitori o kun fun ibanujẹ ati okunkun. Amọ ọmọ rẹ, Duke ati Duchess of York yapa, Princess Anne ati Captain Mark Phillipsyapa nigba ti Prince ati Princess ti Wales.

Ọpọlọ awọn eniyan lo bu ẹnu atẹ lu bi ko se kọkọ sọrọ lasiko iṣẹlẹ Diana, amọ Ọbabinrin naa pa ero rẹ da, to si ba awọn eniyan sọrọ wi pe oun ba wọn kẹdun iṣẹlẹ naa.

Queen Elizabeth II

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun ọpọlọpọ ọdun ni Ọbabinrin Elizabeth ko fi rin irinajo amọ awọn eniyan mọ gẹgẹ bi onkawe, to fẹran lati ma aka iwe, gbogbo ohun to ba wa si iwaju rẹ ni yoo ka yẹbẹ yẹbẹ.

Awọn olubasisẹ pọ rẹ fi lede bi o ṣe ma n lo wakati mẹta ni ojoojumọ lati ka gbogbo ohun ti wọn ba fi ranṣẹ si gẹgẹ bi atẹjiṣẹ , ti yoo si fi gbogbo rẹ si ọkan lai gbagbe nkankan.

The Queen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nipa ti oṣelu, oun lo ma n fa ọwọ eniyan ti yoo ṣejọba silẹ, ti Olootu ijọba ba fi ipo silẹ tabi ti nkan miran ba ṣẹlẹ, amọ lati igba ti ẹgbẹ oṣelu Conservative ti n yan adari fun ara wọn ni nkan ti yipada. Ọbabinrin naa ko nilo lati dasi ọrọ oṣelu wọn.

Obabinrin naa sa gbogbo ipa rẹ lati ṣejọba pẹlu ipa rẹ lai wẹyin wo.O jẹ ẹni to ni irẹlẹ ọkan, to mọ oye, to si ni ibọwọ, to sis ̣e ohun gbogbo pẹlu ọkan kan ati igboya.

1px transparent line