New Kind of England: Charles dí Ọba tuntun Ilẹ̀ Gẹẹsi

Ọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, © Nadav Kander

Ni kete ti Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi waja ni itẹ ọba kuro lai si aṣẹyẹ lọ si ọdọ ọmọkunrin rẹ akọkọ, Charles, to jẹ Ọmọbakunrin Wales tẹlẹ.

Amọ awọn aṣeyẹ wa ti wọn yoo ṣe lati ṣe lede lẹyin ọba to waja ati gigori itẹ ọba tuntun

Kini wọn yoo pe orukọ rẹ?

Orukọ ti wọn yoo maa pe ni Ọbakunrin Charles Kẹta

Iṣẹ akọkọ ti yoo ṣe niyii lati sọ orukọ to fẹ ki wọn pe oun ninu awọn orukọ rẹ bii Charles Philip Arthur George.

Amọ kii ṣe oun nikan ni aye rẹ yoo yipada.

Bio tilẹ jẹpe oun ni ade ọba kan, Ọmọbakunrin William ko ni da Ọmọbakunrin Wales ni kiakia amọ yoo jẹ oye baba rẹ miran bi Duke ti Cornwall, ti iyawo rẹ yoo si da Duchess Cornwall.

Iyawo Ọba naa yoo gba orukọ tuntun ti wọn yoo maa pe e ni queen Consort- Consort ni wọn n pe iyawo Ọba.

Ayẹyẹ gigori itẹ

Lẹyin wakati mrinlelogun ti wọn ba kede pe ọba waja ni wọn yoo kede Charles gẹgẹ bi Ọba. Ni aafin ọba St James ni ilu London ni ayẹyẹ naa yoo ti waye lawujọ awọn afọbajẹ ( Ajọ Accession Council)

Awọn to wa ni ajọ afọbajẹ naa ni awọn aṣofin tẹlẹri ati isin yii, awọn agbaagba ni ajọ Commonwealth ati Lord Major Ilu London

Ọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, PA Media

O kere tan ẹẹdẹgbẹrin awọn eniyan ni yoo pejọ pọ sibẹ lati ṣe ayẹyẹ naa. Ni eleyii to kọja, igba eniyan lo pejọ sibẹ.

Ọba kii wa nibẹ.

Nibẹ ni wọn yoo ti kede iku ọbabinrin Elizabeth gba ẹnu aarẹ Privy Council (Penny Mordaunt MP) .

O ṣeeṣe ki ọrọ yipada amọ adura ni wọn saba ma n gba, ti wọn yoo si sọ ọrọ iwuri nigba ọba to waja, ati erongba wọn nipa ọba tuntun.

Awọn igbimọ yii yoo buwọlu ọrọ naa to fi mọ Olotu Ijọba ati Archbishop Canterbury ati Lord Chancellor.

Bakan naa ni wọn yoo ṣakiyesi ohun ti ko si nibẹ to yẹ ko wa nibẹ.

Aṣẹ akọkọ lati ẹnu Ọba

Lẹyin eyi ni awọn afọbajẹ naa yoo ṣepade lẹyin ọjọ kan, ti ọba naa yoo si wa nibẹ pẹlu awọn Privy Council.

Ko si iburawọle fun Ọba lati igba laelae ni Ilẹ Gẹẹsi bi awọn aarẹ orilẹede miran, amọ Ọba yoo paṣẹ tabi ba awọn eniyan sọrọ gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe.

Ọba naa yoo jẹ ẹjẹ lati ri pe ile ijọsin Church of Scotland duro laelae.

Queen Elizabeth II ati Ọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

1px transparent line

Lẹyin ti awọn onifere ba fun fere wọn tan, ni wọn yoo kede ni Charles ni gbangba gẹgẹ bi ọba tuntun.

Ori apele ni St.James Palace ni wọn yoo ti kede, ti yoo si pariwo - Ki Ọlọrun doola ẹmmi ọba ( God Save the King)

Ifọbajẹ

Pabanbari ifọbajẹ naa ni ayẹyẹ igori itẹ ti wọn yoo gbe ade ọba le Charles lori.

Nitori ọpọlọpọ ayẹyẹ to rọmọ ifinijọba yii, kii waye ni kiakia.

Nigba ti Ọbabinrin Elizabeth, ọdun 1952 lo gori itẹ amọ ọdun 1953 ni wọn ṣe ayẹyẹ fun.

Lati bi ọdun 900, Westminster Abbey William ni ayẹyẹ naa ti ma n waye nibẹ ni ọba akọkọ ti gori itẹ, ti Charles yoo si jẹ ọba ogoji ti yoo jẹ.

Ijọ Anglican nim yoo ṣe ayẹyẹ naa, ti Archbishop Canterbury yoo si ṣakoso rẹ.

Ọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Mirrorpix / Getty Images

1px transparent line

Nibẹ ni wọn yoo ti fi ade wura ti Ọba Edward, ti wọn ti ṣe lati ọdun 1661.

Ijọba ni yoo san owo ayẹyẹ yii nitori ayẹyẹ ijọba ni, awọn ni yoo si sọ airu eniyan ti yoo wa sibẹ.

Ọpọlọpọ orin yoo wa pẹlu ọpọlọpọ kika ati fifi ororo yan ọba tuntun naa.

Olori Ajọ Commonwealth

Charles ti da adari ajọ Commonwealth to ni orilẹede mẹrindinlọgọta ati eniyan to le ni biliọnu meji.

Fun bi orilẹede mẹrinla to fi mọ UK ni ọba naa jọba le lori.

Awọn orilẹede to wa ninu ajọ naa ni Australia, Antigua and Barbuda, the Bahamas, Belize, Canada, Grenada, Jamaica, Papua New Guinea, St Christopher and Nevis, St Lucia, St Vincent and the Grenadines, New Zealand, Solomon Islands to fi mọ Tuvalu.

Ọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo aworan lo gba ontẹ