NDLEA: Báyìí ni ọwọ́ wa ṣe tẹ 'Iya Ilorin' àti DPO tó ń ṣòwò oògùn olóró ní Eko

Oríṣun àwòrán, Facebook/NDLEA
Ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni Naijiria NDLEA ti kede pe awọn ti ri ẹgbẹrun mejilelogun kilo oogun oloro codeine,metha ati Loud gba nilu Eko
Alukoro Femi Babafemi sọ pe ọwọ awọn tun tẹ DPO kan,Monday George Chika ti wọn ti ṣaaju le lẹnu iṣẹ fẹsun to jọ mọ oogun oloro.
Ọwọ tun tẹ ẹ pada ni Mokwa lori ẹsun to le kuro lẹnu iṣẹ tẹlẹ lasiko ti wọn ka igbo 280 ti wọn di papọ ti o to iwọn kilo 168kg mọ lọwọ.
DPO abanilorukọjẹ yi nikan kọ ni wọn sọ pe ọwọ awọn tẹ,alabaṣe rẹ kan Emmanule Eniola naa ko si panp ajọ NDLEA.
Atẹjade naa tun sọ pe ọwọ tẹ arabinrin ẹni aadọta ọdun kan Jemilat Seriki ti inagijẹ rẹ n jẹ Iya Ilorin nilu Eko .
Babatunde sọ pe o ti pẹ t'awọn ti n tọ pinpin arabinrin Seriki to lawọn fura si pe o jẹ ọkan lara awọn to ni oogun oloro Loud 12,385 ti wọn gbe wọ Naijiria lati Ghana.
Lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun to kọja lo ni awọn ti da oogun oloro yi lọna ni Eko Atlantic Beach Victoria Island nilu Eko.
NDLEA sọ pe Iya Ilorin ti jẹwọ pe oun wa lara awọn to ni oogun oloro ti wọn n wi yi ati pe wọn kọ ọrọ ''Jah Bless'' sori apo oogun oloro to jẹ toun.
Bakan naa ni ọwọ tẹ awọn obinrin marun un mii lara awọn afurasi mẹtadinlogun ti wọn lọwọ si oogun oloro Methamphetamine kilo 3,727.72 ladugbo Akala ni Mushin.
Lọjọ Kẹta oṣu Keji ọdun yi ni wọn mu wn lowurọ kutu.
Ipenija oogun oloro ni Naijiria n peleke si
Ọjọ ti pẹ tawọn to n gbogun ti lilo oogun olori ni Naijiria ti n koju orisi eeyan to n kopa ninu owo buruku yi.
Ọrọ yi jẹ eleyi to kọ ọpọ lominu nitori bi awọn ọdọ Naijiria ṣe n lo oogun oloro yi yala fun igbafẹ tabi lati fipa ironu rẹ.
Aimọye lo ti dero ọrun lẹyin ti wọn lo oogun oloro yi tawọn mii si ti di alangana nitori lilo oogun oloro.
Bi a ko ba gbagbe BBC ṣe iwadii ọtẹlẹmuyẹ kan to ṣafihan aburu ati ewu to wa ninu lilo oogun oloro taa pe akọle rẹ ni Sweet Sweet Codeine.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ Orilé-ede Naijiria fofin de gbigbe Codeine wọle lẹyin iwadii ile iṣẹ wa (BBC) lori bi àwọn ọdọ ṣe n ṣìí lo.
Ṣugbọn igbesẹ yii nikan kọ lo le fopin si àṣìlò oogun oloro ni Naijiria.
















