Olubadan: Aáwọ̀ ń parí láàrín ìgbìmọ̀ lọ́ba-lọ́ba nílẹ̀ Ibadan

Dukuu to n jẹyọ laarin Olubadan atawọn agba oye ti ijọba ana ni ipinlẹ Ọyọ gbe ade le lori, n ṣebi eyi ti n jẹ rodo lọ momi bayii.
Ni ọjọ Aje ni awọn agba oye to jẹ igbimọ Olubadan lọ ṣe baba kẹẹ pẹ si Olubadan laafin rẹ ni Popoyemọja nilu Ibadan, lasiko ayẹyẹ to fi n sami ọjọ ibi ọdun kọkanlelaadọrun rẹ loke erupẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ṣiṣẹ́ takò mí ní Ireland kí ń má baà wọlé ìbò Káńsélọ̀ - Yemi Adenuga
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Irọ́ ńlá! Ẹgbẹ́ IPOB ò tako Ààrẹ Buhari ní Japan- Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
Pataki ohun toju ri nibi abẹwo wọn naa ni pe awọn agba oye naa ko wa pẹlu ade wọn, ti wọn si dọbalẹ gbalaja lati ki Olubadan.
Lara awọn agba oye mẹsan ilẹ Ibadan, mẹfa lo wa nibi abẹwo naa. Iyẹn Otun Olubadan, Lekan Balogun ati Balogun Owolabi Olakulehin.
Awọn yoku ni Osi Balogun Tajudeen Ajibola; Asipa Olubadan, Eddy Oyewole; Ekarun Olubadan Amidu Ajibade ati Ekarun Balogun Kola Adegbola.

Nibẹ ni wọn ti darapọ mọ awọn agba oye yoku bii Iyalode ilẹ Ibadan, Oloye Theresa Oyekanmi; Agbaakin Olubadan, Lekan Alabi atawọn Mọgaji ati Baalẹ.
Laipẹ yii ni iroyin gbe e pe, awọn agba oye ti wọn gbe ade le lori naa ti fi igba kan faake kọri pe, ko sẹni to lee gba kanbo lọwọ imu, ko si ẹni to lee gba ade naa lori awọn.
Sugbọn Olubadan ko dẹkun ipe rẹ pe gbogbo awọn agba oye naa lo gbọdọ gbe ade wọn silẹ nitori ọba meji kii wa ni aafin.
- Èdè Akurẹ àti Ibadan ni wọ́n fi fà mí léti pé ẹni re kìí 'se òṣèlú - Seyi Makinde
- ‘Pussypedia’ rèé, ojú òpó tó ń mú àdínkù bá ìṣòro ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin
- Ìkúnlẹ̀ àbiyamọ o! Saudi fẹ́ gbẹ̀mí 23 ọmọ Nàìjíríà tó gbé òògùn olóró
- Irọ́ ló pa, a kò mọ̀ ọ́ rí tàbí fún ọ ní ₦13m - APC tako afurasí ajínigbé
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú mi lẹ́rú ní 1837 - Ajayi Crowther
Ọpọ lo ti n ri igbesẹ ọjọ Aje naa gẹgẹ bii eyi ti o n ṣe afihan pe, alaafia ti n pada si aarin igbimọ lọbalọba ilu Ibadan.












