Wo àwọn ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ajọ àwọn gomina Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter/Kayode Fayemi
Gomina Ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ni alaga tuntun awọn gomina lorilẹ-ede Naijiria bayii.
Lalẹ Ọjọru ni Fayemi di alaga tuntun awọn gomina lẹyin idibo- afọwọ sii to waye nibi ipade awọn gomina lolu-ilu Naijiria, Abuja.
Fayemi to jẹ minisita tẹlẹ fun ẹka iwakusa ati irin ni ibo to le ni ida aadọrin lati jawe olubori ninu ibo ọhun.
Gomina Ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, ati ti Delta, Ifeanyi Okowa lo fa Fayemi kalẹ fun didije ninu idibo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Gomina Abdul Aziz Yari lati ipinlẹ Zamfara lo ju awà silẹ lẹyin to ti tukọ ajọ naa lẹẹmeji laarin ọdun mẹrin
Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ni igbakeji fun Fayemi ninu ajọ awón gomina lorilẹ-ede Naijiria.
Gomina Fayemi yoo gbajọba lọwọ Gomina ipinlẹ Zamfara Abdul-aziz Yari Abubakar ti ijọba rẹ tan lalẹ Ọjọru.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Saaju ni gomina Dickson tipinlẹ Bayelsa ti ni awọn gomina lati ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni dije dupo alaga naa lasiko yii.
Ni kete ti wọn yan Fayẹmi tan lo ti parọwa fawọn akẹgbẹ rẹ lati tubọ mojuto ọrọ eto aabo Naijiria to ti n gbẹbọ lọwọ koowa bayii.
Ohun to yẹ koo mọ nipa ajọ gpmina Naijiria
Ọdun 1999 ni wọn da ajọ awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria silẹ.
Wọn daa silẹ pẹlu erongba pe ki awọn gomina le maa mojuto ohunkohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria bẹrẹ lati ipinlẹ koowa wọn.
ọpọ igba ni igbesẹ ajọ awọn gomina yii maa n yatọ si ti ijọba apapọ bii aifẹnuko lori odiwọn iye owo ọya awọn oṣiṣẹ eyi to yatọ lati ipinlẹ kan si ikeji.
Lọwọlọwọ ni ẹnu wọn kò kò lori sisan owo sapo awọn alaga ijọba ibilẹ bi o ti yẹ ni eyi tijọba apapọ ṣẹṣẹ fẹ mojuto lasiko yii.
Lọdun 2017 ni wọn tun forigbari nigba ti ajọ EFCC to n risi ọrọ ṣiṣe owo ilu ni mọkumọku fẹ tojubọ bi wọn ṣe n na owo iranwọ ojiji ti Paris Club tijọba apapọ pin fun wọn.
Kinni o mọ nipa Kayode Fayemí?
Kayode Fayemi jẹ ọmọ Ilu Isan-Ekiti ni ijọba ibilẹ Oye nipinlẹ Ekiti.
Ọjọ kẹsan an, oṣu keji, ọdun 1965 ni wọn bi Ọmọwe Fayemi.
Fayẹmi ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ kaakiri ilẹ Afirika, Yuropu, Amẹrika ati ilẹ Asia.
Fayemi jẹ Gomina ipinlẹ Ekiti lọdun 2010 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria (ACN).
Ọmọwe Fayẹmi tun ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi oniroyin, oniṣẹ iwadi ati olugbani-nomọran lori ọrọ idagbasoke tẹlẹ ri.
Fayemi gẹgẹ akọkọ ni ilẹ iwe giga fasiti Ilu Eko(UNILAG), bẹẹ lo gba oye keji ni fasiti Ile Ife.
Fayemi gba oye Ọmọwe ni Fasiti Kings College niluu London.
O ṣe igbeyawo pẹlu Olabisi Fayemi, wọn si bi ọmọ.


















